Ọbasanjọ:Buhari mase ko imọran baba mi danu-Iyabọ

Iyabọ Obasanjo Image copyright Twitter
Àkọlé àwòrán Iyabọ Obasanjo nfẹ kijọba Buhari mu imọran baba rẹ lo

Awuyewuye to n waye lori lẹta ti Oloye Olusẹgun Ọbasanjọ kọ si aarẹ Muhammadu Buhari ko tii jẹ rodo, lọ ree mumi rara.

Idi ni pe arẹmọbinrin fun Oloye Ọbasanjọ, Iyabọ, ti faraya lori lẹta kan to kọ si baba rẹ ldun 2013, tawọn eeyan kan tun n pin kiri pe o sẹsẹ kọ lati fi tako baba rẹ ni.

Iyabọ, to tun ti jẹ asofin agba lorilẹede yi nigbakanri ni, iyalẹnu lo jẹ fun oun nigba ti oun ka bi ọrọ naa se n ja rain-rain lori ẹrọ ayelujara.

Ninu atẹjade kan to fi sita, iyabọ ni iru iroyin bayii jẹ ọgbọn alumọkọrọyi awọn alatilẹyin fun ijọba Buhari lati pa awọn ọrọ to se patakii, to jẹyọninu lẹta baba oun ti ni, eyi to jẹ ara awọn isoro ti orilẹede Naijiria n koju lọwọ.

Senatọ Iyabọ Ọbasanjọ ni kaka ki awọn amugbalẹgbẹ aarẹ Buhari maa lo lẹta toun ti kọ lati ọjọ pipẹ gẹgẹbi ohun eelo lati bo iwa ainikanse ijọba Buhari mọlẹ, o ni nse lo yẹ ki wọn mu awọn koko imọran ti baba oun fun ijọba aarẹ Muhammadu Buhari lo ni.

O ni orilẹede Naijiria ni isoro to pọ to si nilo amojuto ni kiakia.

Iyabọ ni oun ko ni ibasepọ kankan pẹlu ijọba Naijiria lati igba ti oun ti kuro ni ile igbimọ asofin agaba ni ọdun 2011, ati pe iwa ainitiju lati maa lo orukọ oun fun irufẹ awọn ọrọ ti ko ni itumọ bẹẹ.

Related Topics