Aarẹ Ọna Kakanfo:Isẹ rẹ ni ko dena idunkoko ajeji nilẹ Yoruba

Oloye Gani Adams, Aarẹ Ọna Kakanfo tuntun
Àkọlé àwòrán Ojuse Aarẹ Ọna Kakanfo ni lati daabo bo ilẹ Yoruba lọwọ ikọlu awọn ajeji

Akọwe apapọ fun ẹgbẹ agbaagba ilẹ Yoruba (YCE), Dokita Kunle Ọlajide ti kede pe omi n bẹ lamu fun Oloye Gani Adams, tii se Aarẹ Ọna Kakanfo ti wọn sẹsẹ yan fun ilẹ Yoruba.

Oloye Ọlajide woye ọrọ yi lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ pẹlu afikun pe awọn agbaagba ilẹ Yoruba ti sin Aarẹ tuntun ni gbẹrẹ ipakọ pe asiko to se pataki pupọ ninu itan ilẹ Yoruba ati Naijiria lo gba ipo naa.

O ni oniruuru idunkoko mọ ni, ifiyajẹni ati ibẹru lo gba ilẹ yi kan lasiko yi, to si dabi ẹnipe oju ọrun su dẹdẹ lai rọ ojo, nitori naa, isẹ nla lo n bẹ niwaju Aarẹ Ọna Kakanfo tuntun lati ri daju pe aabo to peye wa lawọn ẹnu bode to wọ ilẹ Yoruba.

Gbogbo awọn ẹgbẹ ọdọ nilẹ Yoruba ni Aarẹ yoo kojọ tako idunkoko awọn ajeji.

"O da wa loju pe Oloye Gani Adams kaato lati se ojuse Aarẹ Ọna Kakanfo la se sugba rẹ lati jẹ oye naa, ti yoo si se aseye, ti alakan n se epo, nitori ilẹ Yoruba ko ni faaye gba kawọn ajoji gba ilẹ wa mọ wa lọwọ.

Oloye Ọlajide ni oniruuru ẹlẹgbẹjẹgbẹ to jẹ ti ọdọ nilẹ Yoruba ni Oloye Adams yoo ko jọ, kii si se ẹgbẹ OPC nikan, to fi mọ ọpọ ẹgbẹ awọn agbaagba pẹlu, to fi mọ YCE, awọn ọba alaye, ati oloselu lati ri daju pe a le awọn eeyan to ba fẹ dunkoko mọ wa jinna tefetefe.