Gbajugbaja eto BB Naija fun 2018 g'ori afẹfẹ

Eto Big Brother Naija ti ọdun 2018 Image copyright BBNaija Official Site
Àkọlé àwòrán Eto naa ti ọdun to kọja jẹ aseyọri nla

Abala ikẹẹta gbajugbaja eto agbelewo to nipa ju nilẹ Afirika, Big Brother Naija ti bẹrẹ lonii ọjọ aiku, ọjọ kejidinlọgbọn osu kini pẹlu iside nla.

O jẹ eto ti gbogobo ololufẹ rẹ ti nreti, o fa oju ọpọlọpọ ọmọ Naijiria mọra bẹẹ si ni o tayọ orilẹede Naijiria nikan si awọn orilẹede mii nilẹ Afirika nitori oniruuru alakalẹ eto to ndani lara ya ti wọn gbe kalẹ fun awọn akopa lati se.

Awọn nnkan amunudun yii gaan ni gbogbo eniyan ti nduro de gẹgẹ bi awọn akopa ti wọn ti yan laarin ọpọlọpọ awọn ti wọn jọ forukọ silẹ ti awọn kan si ti ja yoo tun maa figagbaga ninu ile kan naa pẹlu oniruuru idanwo bii ere ojukoroju ti wọn gbe ka iwaju wọn.

Ẹka katakara ile isẹ Multichoice to se agbekalẹ eto naa pẹlu awọn onigbọwọ wọn sọ pe lai si ani ani, abala ọtun eto yii seleri lati jẹ eyi to dun ju ninu gbogbo apapọ eto Big Brother to wa nilẹ Afirika.

Wọn fi aridaju han fun awọn ololufẹ eto naa wipe wọn o kan ni gbadun rẹ lasan sugbọn se ni wọn ko ni le yin in kuro loju opo ti wọn ti n wo o titi ipari rẹ ti wọn yoo kede ẹni to jawe olubori.

Eto naa ti ọdun to kọja jẹ aseyọri nla eleyi to ti fa oju ọpọlọpọ ti ko tilẹ mọ nipa rẹ mọra.