Super Eagles bori Angola, wọn yoo koju Sudan

Awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles n yọ Image copyright CAF
Àkọlé àwòrán Super Eagles yoo dojukọ Sudan ninu idije ti o kọgun si asekagba idije CHAN ni ọjọru

Awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti orilẹede Naijiria ti fi oju awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Angola dọnrin ninu idije CHAN ti o n lọ lọwọ ni orilẹede Morocco.

Ọmọ ẹgbẹ Eagles wa latẹhin ki wọn to fi agba han Angola pẹlu amin ayo meji si ẹyọ kan lalẹ ọjọ aiku ni Tangiers.

Anthony Okpotu ati Gabriel Okechukwu gba bọọlu wọle fun ẹgbẹ Eagles lẹhin ti Angola ti ni ami ayo kan labala akọkọ.

Image copyright CAF
Àkọlé àwòrán Anthony Okpotu ati Gabriel Okechukwu gba bọọlu wọle fun Eagles

Pẹlu igbiyanju awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Angola lati da ami ayo yii pada, ikọ ti akọni-mọọgba Salisu Yusuf se alakoso yari ti wọn dẹ jawe olubori lẹhin ti wọn ti se afikun fun asiko idije naa.

Ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles yoo dojukọ Sudan ninu idije ti o kọgun si asekagba idije CHAN ni ọjọru.