Ikọlu Daradaran: Ibẹru mu awọn eniyan n'ipinlẹ Ogun

Ọdọmọde Fulani darandaran kan pẹlu awọn ẹran Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Naijiria ti n koju ipaniyan ati ipafara awọn afurasi Fulani darandaran fun igba die

Awọn ọlọpa ipinlẹ Ogun n rọ awọn olugbe ipinlẹ naa lati dẹkun ibẹru-boju ati ipalara pẹlu ireti ikọlu awọn Fulani darandaran gẹgẹbi iroyin naa se ruyọ lopin ọsẹ ti o kọja nilu Abẹokuta.

Agbẹnusọ ọlọpa, ASP Abimbọla Oyeyẹmi sọ fun BBC pe awọn ọlọpa ti pese awọn ikọ ọlọpa lati ṣe ayẹwo ati ṣawari awọn eniyan ti o to bii ogun ti wọn wọlu wa lati ibilẹ Kaiama ni Ipinlẹ Kwara wa si agbegbe Opeji ni Abeokuta lọjọ ẹti.

ASP Oyeyẹmi wi pe lootọ ni wipe awọn Fulani darandaran ogun lati ipinlẹ Kwara de si agbegbe Opeji lori ipe ti Baale agbegbe naa pe wọn lori ajọṣepọ rẹ pẹlu wọn lati pese ibi ijẹun fun awọn ẹran maaluu wọn ni agbegbe naa.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Awọn ọlọpa mu awọn eniyan kan lẹhin iṣẹlẹ naa ṣugbọn fi wọn silẹ nitoripe wọn se akiyesi pe awọn kọ ni wọn se ikọlu naa.

O n bẹ awọn eniyan lati lọ si awọn ile-iṣẹ ati ọja wọn deede laisi ibẹru ipaniyan tabi ipalara lati ọdọ ẹnikẹni bi awọn ọlọpa ati awọn eleto ile-isẹ aabo miiran ti wa lori ni pẹsẹ lati rii daju pe aabo to peye wa fun gbogbo eniyan.

Olugbe Opeji kan, Babatunde Adesola sọ fun BBC pe nnkan ibẹru nla o jẹ fun awọn lati ri ọpọlọpọ awọn Fulani darandaran wọ ilu wa.

O sọ pe ikọlu ati ipanilara t'o sẹlẹ si awọn olukọ ile-iwe meji ninu Ile-ẹkọ akọbẹ ti Atọla ni agbegbe ijọba ibilẹ Ewekoro ti n d'ẹru ba awọn eniyan ti ipinlẹ naa.

Awọn ọlọpa mu awọn eniyan kan lẹhin iṣẹlẹ naa ṣugbọn fi wọn silẹ nitoripe wọn se akiyesi pe awọn kọ ni wọn se ikọlu naa.