Ijamba Ondo: Eniyan mejila padanu ẹmi

Ọkọ akero kọlu awọn eniyan ni Ondo Image copyright SOLA ILESANMI/ORANGE FM
Àkọlé àwòrán Iru ijamba bayi wọpọ loju ọnọ marosẹ

Ojo buruku esu gb'omimu ni, nipinlẹ Ondo, nigbati ijamba ọkọ meji ọtọọtọ pa eniyan mẹwa ni agbegbe Akungba Akoko ati oju-ọnọ Ajibamidele ni popona marose Benin-Ọrẹ-si Eko nipinlẹ Ondo.

Iroyin sọ pe eniyan marun pẹlu iya arugbo kan ati awọn ọmọ-ọmọ rẹ ni wọn padanu ẹmi wọn ni Akungba-Akoko, nigba ti ọkọ akero kọlu wọn, ni ẹgbẹ ọnọ ọja Ibaka ni agbegbe Ile-ẹk giga fasiti ti Akungba Akoko.

Ẹni ti isẹlẹ naa soju rẹ, ọgbẹni Muritala Rauf salaye wi pe ọkọ akero naa to n bọ lati agbegbe Ikarẹ ni o padanu ijanu ọkọ rẹ, ti awakọ si duna-dura lati yẹwọ fun ọkọ ayọkẹlẹ ti o wa lẹgbẹ ọja naa.

Image copyright SOLA ILESANMI
Àkọlé àwòrán Ajọ FRSC n parọwa fun awọn awakọ lati dẹkun ere asapajude

Rauf wi pe ọpọlọpọ awọn oluraja ati onisowo ti o farapa ninu ijamba naa ni wọn ti ko lọ si ile-iwosan, ti awọn osisẹ ajọ FRSC ati ọlọpa si korajọ lati da alafia pada si agbegbe naa.

Olori osisẹ ajọ to nrisi eto irina lojupopo, (FRSC) nipinle Ondo, ọgbẹni Vincent Jack nigba ti o fi idi isẹlẹ naa mulẹ, sọ wi pe eniyan mẹrin lo padanu ẹmi wọn, ti eniyan meji si parapa.

Bakan naa, awọn ti ọrọ naa soju wọn sọ pe ijamba ọkọ ti o waye ni popona marose ọrẹ waye latari bi ọkọ ayọkẹlẹ meji se n sare asapajude lati le wọ iwaju ara wọn. Eleyi ti o jasi ikọlu lojiji, ti o si la ẹmi eniyan meje lọ.

Image copyright SOLA ILESANMI
Àkọlé àwòrán Awọn eniyan meje padanu ẹmi ninu ijamba

Olori awọn osisẹ FRSC lagbegbe naa, Olusẹgun Ogungbemi sọ pe sisare asapajude loju popo lo s'okunfa ijamba naa, ti o si parọwa fun awọn arinrinajo ati awakọ lati maa se pẹlẹ loju popo.