Naijiria da ọmọ orilẹede Cameroon mejila pada s'ile

Awọn ti wọn n ja fun ominira agbegbe to wa fun awọn eledee-Gẹẹsi ni Cameroon Image copyright @fragov.org
Àkọlé àwòrán Ijọba apapọ ju awọn mẹfa si itimọle awọn olofintoto orilẹede yi

Ijọba orilẹede Nigeria ti le ọmọ Cameroon mejila ti wọn n ja fun ominira agbegbe to wa fun awọn eledee-Gẹẹsi ni Cameroon pada sile.

Awọn mejila naa ni wọn fi panpẹ ọba gbe l'osu yi, lẹyin ti wọn sa asala fun ẹmi wọn lati orilẹede Cameroon, ti wọn si wa se atipo lorilẹede Nigeria.

Agbejoro fun awọn to n pe fun ominira naa, Fẹmi Falana sọ wipe ijọba apaapọ fi panpẹ ọlọpa gbe awọn ọmọ Cameroon naa ti adari wọn njẹ, Julius Ayuk Tabe ati awọn mọkanla miran, ni ile igbafẹ Nera Hotels ni Abuja.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Awọn elede Gẹẹsi ọmọ orilẹede Cameroon n ja fun ominira agbegbe wọn

Falana fikun wipe awọn mẹfa ninu wọn ni ijọba apapọ fi si itimọle awọn olofintoto orilẹede yi (NIA), ki wọn to o fi wọn silẹ, ki wọn ma pada si ilu wọn.

Agbejọro naa fesun kan ijọba apapọ wipe wọn ko je ki ohun, ẹbi ati onisegun oyibo fi oju kan wọn nigba ti wọn fi wa ni atimọle. Amọ, igbakeji asoju fun ajọ agbaye to n risi ọrọ aririnajo si orilẹede Nigeria ati ajọ ECOWAS, Brigitte Mukanga-Eno nikan ni wọn fun laye lati yọju si wọn nigba ti wọn wa latimọle.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ijọba Cameroon dunnu pẹlu bi ijọba Nigeria se da awọn eniyan naa pada sile

Ti a ko ba gbagbe, ijọba Muhammadu Buhari ni awọn eniyan kẹgan, wipe wọn ko fun awọn ọmọ orilẹede Cameroon to ja fun ominira agbegbe wọn naa ni aabo to peye, eyi to tapa sofin orilẹede Nigeria to faye gba ki wọn gba awọn to ba sa asala fun ẹmi wọn tọwọ-tẹsẹ.

Iroyin fi lede wipe ijọba orilẹede Cameroon dunnu pẹlu bi ijọba orilẹede Nigeria se da awọn eniyan wọn naa pada sile, lati foju wina ofin nitori wọn n pe fun iyapa agbegbe ti awọn ọmọ Cameroon elede Gẹẹsi wa.