Ọọni Ilẹ Ifẹ: Isọkan ni a nilo lorilẹede Naijiria

Ooni ti Ilẹ-Ifẹ, Alayeluwa Adeyeye Enitan Ogunwusi pẹlu Sultan ti Sokoto Image copyright Ooni Palace
Àkọlé àwòrán Ooni pe fun ifọwọsowọpọ Nigeria

Ooni ti Ilẹ-Ifẹ, Alayeluwa Adeyeye Enitan Ogunwusi - Ojaja 11, ti pe fun agbajọwọ ati isọkan awọn lọbalọba lati f'opin si ija ati asọ ni orilẹede Naijiria.

Oba Ogunwusi ti o jẹ alaga fun ajọ awọn ọba to wa lagbeegbe gusu Naijiria, sọ eyi nibi apejọ awọn lọbalọba to waye ni n'ilu Port Harcourt ni ipinle Rivers.

Ogunwusi nigba to n dupẹ lọwọ Gomina Wike to gbawọn lalejo, sọ pe apejọpọ awọn ọba naa wa fun wiwa ọnọ lati jẹ ki isọkan ati ifọwọsowọpọ awọn ọba o f'idi mu'lẹ sii lorilẹede yii.

Image copyright Ooni Palace
Àkọlé àwòrán Awọn ọba wipe pataki ni isọkan laarin gbogbo ẹya ilẹ lorilẹede yi

O fi kun ọrọ naa wipe awọn ọmọ orilẹede yi gbọdọ fimọ sọkan lori isọkan orilẹede yii. Ati wipe pataki ni isọkan laarin gbogbo ẹya ilẹ yi, ki idagbasoke le e waye lorilẹede yi.

Oba Ogunwusi to wipe awọn lọbalọba ni akọkọ-kan awọn eniyan, wa kesi awọn ọba lati mase ka'wọ gbera, sugbọn ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu ijọba orilẹede yi lati mu itẹsiwaju ba ọr aje orilẹede yi.

Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ninu ọrọ rẹ, dupẹ lọwọ awọn ọba naa fun isẹ takuntakun ti wọn n se lati ri i wipe orilẹede yi duro ninu isọkan ati ifọwọsowọpọ.

Igba kẹsan niyi ti awọn ọba ni gbogbo ẹkun orilẹede Naijiria yoo se ipade gbogboogbo, lati jijoro lori itẹsiwaju orilẹede yii.