Awọn ọlọpa mu afunrasi janduku merinlelaadota n'ipinlẹ Ọyọ

Awọn ọlọpa mu afunrasi kan Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Lasigbo waye l'ọjọ aje nigba laarin awọn ẹgbẹ Oodua Peoples Congress, OPC

Ọwọ ọlọpa ti tẹ awọn afunrasi janduku mẹrindinlaadọta to ni ibasepọ pẹlu laasigbo to waye l'Oke-Ado ni ilu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ.

Lasigbo to waye l'ọjọ aje bẹrẹ nigba ti awọn ẹgbẹ Oodua Peoples Congress, OPC ti wọn s'orogun ara wọn fija pẹẹta, ti ọpọlọpọ eniyan si farapa ninu isẹlẹ naa.

Awọn eniyan ti isẹlẹ naa soju rẹ wipe ija naa bẹ s'ilẹ laarin awọn ẹgbẹ OPC ti wọn pe ara wọn ni New Era Faction ti OPC ati awọn ẹya miran ti wọn durosinsin lẹyin Aarẹ Ọnọ Kakanfo tuntun, oloye Gani Adams.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ajisebutu ti o kọ lati fi idi rẹ mulẹ wipe laasigbo naa waye laarin awọn ẹgbẹ OPC

Wọn wipe awọn ẹgbẹ mejeeji naa n ja fun isakoso agbegbe Oke-Ado, eyi to sokunfa bi wọn se bẹrẹ si nii kọlu ile itaja ati awọn ile-isẹ to wa lagbegbe naa. Eyi lo mu ki ọrọ naa di boolọ o yago.

Alukoro fun Ajọ ọlọpa, Adekunle Ajisebutu sọ wipe Kọmisọnna ọlọpa ni ipinlẹ naa, Abiọdun Adekunle Odude lọ si ibi isẹlẹ yii, ti o si ri daju wipe alaafia pada sagbegbe naa.

Ajisebutu ti o kọ lati fi idi rẹ mulẹ wipe laasigbo naa waye laarin awọn ẹgbẹ OPC, wipe ọwọ sikun ọlọpa ti mu awọn afurasi mẹrindinlaadọta to fa wahala lagbegbe Oke-Ado ni Ibadan, lẹyin ti awọn ọlọpa yara lọ si ibi isẹlẹ naa.