Grammy 2018: Bruno Mars lo fakọyọ jùlọ

Bruna Mars pẹ̀lú àmì ẹ̀yẹ fún àwo orin tó dára jù lọ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Bruna Mars pẹ̀lú àmì ẹ̀yẹ fún àwo orin tó dára jù lọ

Bruno Mars àti Kendrick Lamar ló gba àmì ẹ̀yẹ tó pọ̀ jùlọ níbi ètò àmì ẹ̀yẹ Grammy fọ́dún 2018 tò wáyé nílúù New York lóríléèdè Amẹ́ríkà.

Mars gba àmì ẹ̀yẹ fún àwo orin tó dára jù lọ; èyí si jẹ́ ìyàlẹ́nu fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tó ti ń rò pé orin Lamar, 'Damn' ni yòó gba a.

Alessia Cara ló gba àmì ẹ̀yẹ olórin tuntun tó peregedé. Èyí ló mú kí ó jẹ́ òun nìkan ni akọrin obìnrin kan tó gba àmì ẹ̀yẹ tó dọ́ṣọ̀.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Orin tí Kesha kọ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ǹkan tó mú kí ètò nàá lárinrin

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó kọrin níbi ètò nàá ló wọ aṣọ̀ òdòdó funfun láti fi ṣe àtìlẹyìn fún àfojúsùn ètò náà #TimesUp and #MeToo, tó dá lóri i ìfipá bánilòpọ̀ àti àìdọ́gba láàrin ọkùnrin àti obìnrin.

Akọrin tàkasúùfe nì, Kesha fakọyọ lásìkò tó kọ orin rẹ 'Praying', èyí tó fi sọ nípa bí óun fúnra rẹ̀ ṣe jàjàbọ́ lọ́wọ́ ìrírí ìfipá bánilòpọ̀.

Awọn olorin bi lady gaga, Rihanna, Miley Cyrus, U2 ati Elton John nàá fi orin to gbamuse dá àwọn olùkópa lárayá.

Related Topics