Benue: Ìjọba Nàijíríà yòó lo àwọn ọmọ ológun láti kojú ìpànìyàn

Àwọn ọmọ ológun ti dúro ṣẹpẹ́ láti kojú wàhálà náà Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn ọmọ ológun ti dúro ṣẹpẹ́ láti kojú wàhálà náà

Ijọba àpapọ̀ Nàijíríà ti ni àwọn ọmọ ológun lòhun yóò lò láti fi òpin sí bí àwọn daran-daran ṣe ń ṣekú pa àwọn aráàlú nípínlẹ̀ Benue, tó wà lẹ̀kùn àárin gbùn-gbùn Naijiria.

Iléèsẹ́ àárẹ ní àwọn ọmọ jàǹdùkú ló ń ṣekú pa àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n tí wọn ń di ẹ̀bi rẹ̀ ru àwọn daran-daran.

Ìjọba gbé ìgbìmọ̀ kan kalẹ̀ láti wá ojútu sí ìpànìyàn tó ń wáyé ní Benue. Àbájáde ìjíròrò ìgbìmọ̀ nàá tí igbákejì àárẹ, Yemi Osinbajo jẹ́ alága rẹ̀ ló ṣe atọ́kùn ìgbésẹ̀ lílo àwọn ọmọ ológun.

Iléèsẹ́ àárẹ ní àwọn ọmọ ológun ti dúro ṣẹpẹ́ láti kojú wàhálà náà.

Iberu-bojo Fulani Darandaran nipinlẹ Ogun

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Naijiria ti n koju ipaniyan ati ipafara awọn afurasi Fulani darandaran fun igba die

Awọn ọlọpa ipinlẹ Ogun n rọ awọn olugbe ipinlẹ naa lati dẹkun ibẹru-bojo ati ipalara pẹlu ireti ikọlu awọn Fulani darandaran gẹgẹbi iroyin naa se ruyọ lopin ọsẹ ti o kọja nilu Abẹokuta.

Agbẹnusọ ọlọpa, ASP Abimbọla Oyeyẹmi sọ fun BBC pe awọn ọlọpa ti pese awọn ikọ ọlọpa lati ṣe ayẹwo ati ṣawari awọn eniyan ti o to bii ogun ti wọn wọlu wa lati ibilẹ Kaiama ni Ipinlẹ Kwara wa si agbegbe Opeji ni Abeokuta lọjọ ẹti.

ASP Oyeyẹmi wi pe lootọ ni wipe awọn Fulani darandaran ogun lati ipinlẹ Kwara de si agbegbe Opeji lori ipe ti Baale agbegbe naa pe wọn lori ajọṣepọ rẹ pẹlu wọn lati pese ibi ijẹun fun awọn ẹran maaluu wọn ni agbegbe naa.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Awọn ọlọpa mu awọn eniyan kan lẹhin iṣẹlẹ naa ṣugbọn fi wọn silẹ nitoripe wọn se akiyesi pe awọn kọ ni wọn se ikọlu naa.

O n bẹ awọn eniyan lati lọ si awọn ile-iṣẹ ati ọja wọn deede laisi ibẹru ipaniyan tabi ipalara lati ọdọ ẹnikẹni bi awọn ọlọpa ati awọn eleto ile-isẹ aabo miiran ti wa lori ni pẹsẹ lati rii daju pe aabo to peye wa fun gbogbo eniyan.

Olugbe Opeji kan, Babatunde Adesola sọ fun BBC pe nnkan ibẹru nla o jẹ fun awọn lati ri ọpọlọpọ awọn Fulani darandaran wọ ilu wa.

O sọ pe ikọlu ati ipanilara t'o sẹlẹ si awọn olukọ ile-iwe meji ninu Ile-ẹkọ akọbẹ ti Atọla ni agbegbe ijọba ibilẹ Ewekoro ti n d'ẹru ba awọn eniyan ti ipinlẹ naa.

Awọn ọlọpa mu awọn eniyan kan lẹhin iṣẹlẹ naa ṣugbọn fi wọn silẹ nitoripe wọn se akiyesi pe awọn kọ ni wọn se ikọlu naa.