2019 Election: Ọbasanjọ ní ìrètí wà pé Nàíjíríà kò ní pẹ́ ní ààrẹ tuntun

Aarẹ Buhari ati Oloye Ọbasanjọ ipade ajọ isọkan awọn orilẹede Afrika, AU

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Aarẹ ana ni orilẹ-ede Naijiria, Oloye Olusẹgun Ọbasanjọ ti kede ni pe ọwọ aarẹ orilẹ-ede yii, Muhammadu Buhari ko ni agbara to lati buwlu iwe adehun okoowo ọfẹ nilẹ Afrika.

Oloye Ọbasanjọ sọ bẹẹ lasiko to n sọrọ ni ilu Bali, lorilẹ-ede Indonesia, nibi idanilẹkọ kan ti wọn fi sọri Babacar Ndiaye nibi ipade banki ayanilowo lagbaye IMF ati banki agbaye, World Bank.

Ọbasanjọ fi kun pe ireti wa pe laipẹ yii ni ilẹ Naijiria yoo ni aarẹ ti yoo buwlu iwe adehun naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ọrẹ Falọmọ: Buhari yóò rí ìbò Yorùbá gbà ju Atiku, Ọbasanjọ lọ

"Ilẹ Afrika ko leebori ibẹru ogun okoowo titi ti yoo fi ni aseyọri bii ida aadọta ninu eto okoowo laarin awọn oril-ede to wa nibẹ."

"Eto okoowo to dara ni adehun naa fun ilẹ Naijiria, ireti si wa pe Naijiria yoo ni aarẹ ti yoo lee fọwọsi iwe adehun ọhun nitori ọwọ aarẹ to wa nipo bayii ko lagbara to."

Ọbasanjọ ati Buhari rẹrin si ara wọn

Ni nkan bi ọjọ diẹ sẹyin ni aarẹ orilẹede yii tẹlẹ ri, Oloye Olusẹgun Ọbasanjọ fi lẹta rẹ si aarẹ Buhari sori ẹrọ ayelujara lori alaye ati iwoye rẹ nipa isejọba ti aarẹ Buhari dari.

Oju ewe mẹtala tan yaan yaan ni lẹta naa ni leyi ti aarẹ ana bẹrẹ pẹlu pe nitori bi nkan se nlọ lorilẹede yii ni oun se kọ lẹta naa jade. O ni "owe Yoruba kan sọ wipe bina o tan lasọ, ẹjẹ o le tan leekana".

O sọ siwaju sii pe "nigba ti mo si wa labule, lati rii daju pe ina inu asọ ku, ẹ o fi saarin ika meji ni, ẹ o si tẹẹ pa titi yoo fi ku. O ma n fi ẹjẹ yi eekana eeyan ni. Lati rii daju pe ko wa si ẹjẹ lọwọ, o ni lati rii daju pe ko saaye fun ina yii lagbegbe rẹ".

Pẹlu iforowero ti Obasanjọ se rẹpẹtẹ, o fi we awọn ohun to ba isẹ isejọba rere jẹ bii isẹ, aisi abo, amojuto to mẹhẹ fun ọrọ aje, aibikita si isẹ ẹni, gbigba ọjẹgẹ laye ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O ni gbogbo eleyi nmu ifasẹyin ba ireti ilọsiwaju, aisi irẹpọ nilu ati aise eto oselu daradara to fi mọ aidọgba n ba wa gbe lọwọlọwọ bi ara ile ni. Bi a ko ba mu gbogbo eleyi kuro, ọwọ wa ko le mọ fun ẹjẹ.

Ọrọ pọ ninu iwe kọbọ eleyi ti Ọbasanjọ ti sọ fun aarẹ Buhari to fi mọ wipe nigbẹyin gbẹyin o gba aarẹ nimọran wipe ko fipo silẹ gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Àkọlé àwòrán,

Ipade ajọ isọkan awọn orilẹede Afrika, AU

Ẹwẹ, nibi ipade apero ajọ isọkan awọn orilẹede ilẹ Afrika, awọn adari mejeeji ya gbogbo eniyan lẹnu pẹlu bi wọn se ki'ra wọn bi ọrẹ, wọn di mọra digba ti wọn si nsọrọ tẹrin tọyayaya bi ẹni wipe ko si aawọ kankan laarin awọn mejeeji ko to di wipe aarẹ tẹlẹri, Abdulsalam Abubakar naa dara pọ mọ wọn ninu ẹfẹ. Koda, wọn tun ke si ra lati jọ ya foto pọ.

Nibi ipade ajọ AU yii ni awọn mejeeji yoo ti kọkọ pade lẹyin lẹta ti Oloye Olusẹgun Ọbasanjọ kọ si aarẹ Muhammadu Buhari.

Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo ti fesi si fidio ati awọn aworan Buhari ati Obasanjo ti wn fi sori itakun Twitter, Instagram ati Facebook nibi ipade ajọ AU ti wọ nfẹyin kẹẹ, ibeere wọn si ni wipe se awọn adari wa ti wa sọ wa di ayo ti wọn nta laarin ara wọn ni?

Ẹnikan tilẹ fesi wipe "njẹ o yẹ ki iru nkan bayii tilẹjẹ koko iroyin ti gbogbo eniyan wa npin kiri?"