Buhari wo ifẹsẹwọnsẹ laarin Nigeria ati Angola nibi ipade AU

Aarẹ Buhari nwo ifẹsẹwọnsẹ ilẹ Naijiria pẹlu Angola lori mohunmaworan. Image copyright @APCNigeria
Àkọlé àwòrán Ifẹsẹwọnsẹ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles pẹlu Angola ti Aarẹ Buhari wo ko rọgbọ rara

Kii se iroyin mọ wipe ikọ agbabọọlu Nigeria kogoja lati kopa nibi ipele to kangun si asekagba idije ife ẹyẹ fun awọn agbabọọlu to n gba bọọlu jẹun ni ilẹ Afirika, CHAN to nlọ lọwọ lorilẹede Morocco.

Sugbọn iroyin ibẹ ni wipe, Aarẹ Muhammadu Buhari ko kuna lati maa se koriya fun awọn agbabọọlu naa.

Lasiko ifẹsẹwọnsẹ ilẹ Naijiria pẹlu akẹgbẹ rẹ lati ilẹ Angola, gba-gba-gba bayii ni aarẹ joko ti ẹrọ mohunmaworan lati wo ifẹsẹwọnsẹ naa.

Lootọ Aarẹ Buhari ko si ni ile lasiko ti ifẹsẹwọnsẹ ọhun fi waye nitori ipade apapọ ajọ isọkan ilẹ Afirika, AU to nlọ lọwọ, sugbọn ko sai waaye lati wo ifẹsẹwọnsẹ naa lori ẹrọ mohunmaworam.

Related Topics