Wahala nilẹ Afghanistan: Ikọ̀ adúnkookò IS kọlu ibudo awọn ọmọogun

Awọn ologun ilẹ Afghanistan Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Awọn ologun ti di gbogbo ọna to wọ ibudo ti ikọlu ti waye

Awọn ọmọogun mọkanla lawọn ikọ adukukulaja IS ti ran lọ si ọrun nibi ikọlu kan to waye ni ilu Kabul lorilẹede Afghanistan.

Ikọlu yii ni yoo jẹ ikẹrin iru ẹ ti yoo waye laarin ọsẹ kan.

Awọn ọmọogun mẹrindinlogun miran ni wọn tun farapa lasiko ti awọn adukukulaja naa kọlu ibudo ẹkọsẹ ologun kan to wa lagbegbe iwọ oorun ilu Kabul, tii se olu ilu Afghanistan.

Amọsa, awọn adukukulaja naa ko fi ara ire lọ pẹlu bi awọn ologun naa se rii daju pe awọn pa mẹrin lara wọn, ti wọn si tun mu enikan, gẹgẹbi agbẹnusọ fun ileesẹ ọrọ abo nilẹ Afganistan,ọgagun agba Dawlat Waiziri se salaye fun BBC.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Awọn ikọlu to waye nilu Kabul lopin ọsẹ ran bii ọgọrun eeyan lọ s'ọrun

Ẹgbẹ adukukulajamọni IS ti kede wipe awọn leku ẹda to wa ni idi ikọlu ọhun.

Ikọlu awọn ẹgbẹ adunkukulajamọni nni, IS ati Taliban, ti gbe ẹnu soke ni osu yii, eyi to si ti ran ọpọlọlọpọ eeyan lọ si ọrun ọsan gangan.

Kikan-kikan ni iro ibugbamu ado oloro pẹlu iro ibọn n dun lasiko ti ikọlu naa bẹrẹ ni nkan bii agogo maarun owurọ ni ilẹ Afghanistan ni ibudo awọn ọmọogun naa.

Meji lara awọn to se ọsẹ yii ni wọn fi ado oloro pa ara wọn, ti awọn osisẹ alaabo si pa meji ki ọwọ to tẹ ẹni kaarun.

Bakanna ni ọgagun agba Dawlat Waiziri to jẹ agbẹnusọ fun ileesẹ ọrọ abo nilẹ Afganistan tun salaye wipe, ibọn AK-47 mẹrin, asọ ado oloro kan pẹlu ohun ija oloro miran ni wọn gba lọwọ awọn adukukulaja adunkoko mọni naa.