Naijiria:Iwadi bẹrẹ lori owo iranwọ epo

Ọkan lara awọn ibudo ifọpo ilẹ Naijria Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Aisi an ibudo ifọpo lo sokunfa sisan owo iranwọ ori epo fun awọn ti o nko epo wọle

Owo toto trilliọnu mẹwa naira lorilẹede Naijiria ti nsan lori owo iranwọ epo, taa mọ si subsidy.

Igbimọ tẹẹkoto ile asofin agba lori ọrọ epo rọbi lo sọ eyi di mimọ nibi ijoko ita-gbangba to nse lọwọ lori lori wahala to n suyọ lori ọrọ owo iranwọ lori eroja epo rọbi.

Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Wahala ọwọn gogo epo lo mu ile asofin agba ilẹ Naijria bẹrẹ si nii tan ina wadi bi owo epo se nlọ

Oniruuru awuyewuye lo ti waye lori ọrọ owo iranwọ epo rọbi lorilẹede Naijiria pẹlu ọkan-o-jọkan iwadi to ti waye saaju asiko yii.

Akọtun iwadi, eyi ti ile igbimọ asofin agba nilẹ Naijiria gunle, ko sẹyin bi ọwọn gogo epo rọbi se nfojojumọ waye eleyi to ti nmu ara kan awọn araalu.

Image copyright @NNPC
Àkọlé àwòrán Ọpọ igba ni awọn ile epo maa nda paro-paro ni ilẹ̀ Naijiria nitori ọwọngogo epo

Alaga Igbimọ tẹẹkoto fun ile asofin agba ilẹ yi to wa fun ọrọ epo rọbi, Sẹnatọ Kabir Marafa ni pẹlu ibi ti nkan de duro bayii, orilẹede yii fẹ mọ iye owo ti jala epo kan ba de lati ilẹ okeere tawọn alagbata epo ti nko epo wọle pẹlu iye owo iranwọ ti wọn ngba lori jala epo kan ti wọn ba ko wọ ilẹ yii.

"Ọpọ ọmọ Naijiria ni ko nigbagbọ ninu iye jala epo ti wọn n ko wọ orilẹede yii, asiko si ti wa to bayii lati mọọ. Kii se eyi nikan, a tun fẹ mọ awọn orilẹede ti wọn ti nko epo wọnyi wa pẹlu triliọnu lọna mẹwa naira ti orilẹede Naijiria ti na."

O ni lẹyin ijoko naa, awọn ọmọ orilẹede Naijria gbọdọ lee mọ pato iye owo iranwọ to wa lori epo bẹntiroolu ati epo kẹrosiini, to fi mọ igbimọ gan-an to nse amojuto epo kaakiri ilẹ Naijiria.

Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Ọpọ awọn alẹnulọrọ lori owo epo nilẹ Naijria ni wọn ti pe ko wa wi tẹnu wọn lori bi nkan se nlọ pẹlu owo iranwọ lori epo

Saaju ninu ọrọ tirẹ, aarẹ ile igbimọ asofin agba nilẹ Naijiria, Sẹnatọ Bukọla Saraki se apejuwe owo iranwọ ori epo rọbi naa gẹgẹbi ọna kan ti awọn kọlọransi ẹda kan n lo lati fun alumọni ilẹ yii gbẹ, ti wọn si ngba ẹgbẹlẹgbẹ owo labẹ eto ti araalu ko lee tan ina wa idi rẹ, eyi ti wọn n pe ni owo iranwọ ori epo rọbi.'

Lara awọn to farahan niwaju igbimọ naa loni ni ajọ elepo rọbi ni Naijiria, NNPC, ajọ to n mojuto idiyele owo epo rọbi ni Naijria, PPPRA, ileesẹ olusiro owo agba ni ilẹ Naijiria, ẹgbẹ awọn alagbata epo to jẹ aladani, IPMAN ati awọn alẹnulọrọ mii ni ẹka epo rọbi ni orilẹede Naijiria.