Malaga:Brown Ideye di aayo agbabọọlu tuntun

Brown Malaga Image copyright Ideye Brown/Twitter
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ agbabọọlu Malaga tọwọ bọ iwe adehun pẹlu Brown Ideye

Atamatase agbabọọlu to jẹ ọmọ orilẹẹde Naijiria, Brown Ideye ti darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Malaga fun osu mẹfa.

Ẹgbẹ agbabọọlu Malaga ti sọ wipe awon ti tọwọ bọwe adehun pelu Atamatase ọmọ orilẹẹde Naijiria naa,ti agbabọọlu ọhun yoo si wa pẹlu wọn fun osu mẹfa.

Lori fọran aworan to gbe soju opo instagram rẹ, Brown sọ wipe ayọ oun kun pẹlu bi oun ti se darapo mọ egbẹ agbabọọlu naa.

Gbajugbaja ẹni ọdun mọkandinlọgbọn naa ti wa ni orilẹede Spain lati ọsẹ to kọja lẹyin to fi ẹgbẹ agbabọọlu rẹ tẹlẹ, Tianjin Teda tile China silẹ .

Nnkan o rọgbọ fun Ideye ni Tianjin nibi ti wọn ti rọ nipo pada si akasọ kẹji ẹgbẹ agbabọọlu rẹ pẹlu bi wọn ti se ra agbabọọlu ọmọ Ghana, Frank Acheampong.