Ondo:O d‘èèwọ̀ láti tí ojú pópó pa fún ayẹyẹ

Gomina Rotimi Akeredolu Image copyright Twitter
Àkọlé àwòrán O ti di eewọ bayi lati da oju irn reluwe kọja ladugbo Ọja Ọba

Ijọba ipinlẹ Ondo ti kede pe lati akoko yi lọ, o ti di eewọ fun ẹnikẹni lati di oju popo pa fun ayẹyẹ kayẹyẹ tabi fun eto okoowo yika tibu tooro ipinlẹ naa.

Nitori idi eyi, gbogbo awọn alaga ni gbogbo ijọba ibilẹ meejidinlogun to wa nipinlẹ naa ni wọn ti pasẹ fun lati ri daju pe ofin yi fẹsẹ mulẹ digbin lawọn ijọba ibilẹ wọn.

Oludamọran si gomina ipinlẹ Ondo fọrọ igboke gbodo ọkọ, Hon Tobi Ogunlẹyẹ lo kede eyi fawọn akọroyin nilu Akurẹ, tii se olu ilu ipinlẹ Ondo.

O fikun pe o ti di ẹsẹ fun ẹnikẹni lati ti oju popo pa nipinlẹ Ondo lai naani bi iru ẹni bẹẹ se kanka to lawujọ tabi iru ipo giga to di mu nitori ina lofin, ko mọ oju ẹni to daa.

Ẹnikẹni to ba tapa sawọn ofin tuntun yi yoo san owo itanran.

Oludamọran fun gomina feto igbokegbodo ọkọ naa tun salaye pe lọgan ni ofin ọhun ti bẹrẹ si ni fidi mulẹ, ti wọn ko si ni fi adi pa ẹnikẹni to ba sẹ sofin naa lori, amọ iru ẹni bẹẹ yoo foju bale ẹjọ.

"ko si iru igbinyanju kankan lati ibikibi ti yoo mu ki ijọba pahunda lori asẹ yi, bẹk si tun ni yoo di ẹsẹ fun ẹnikẹni lati maa fo opopona Ọja Ọba laibikita, ti a ko si tun ni faaye gba ikiri ọja lẹba oju popo ọja naa."

Ko tan sibẹ o, Hon Ogunlẹyẹ tunfikun pe ko si aaye mọ fun ẹnikẹni lati maa da oju irin reluwe kọja tabi maa fo oju irin naa laibikita nitori irufẹ ẹni bẹẹ yoo san owo itanran.