David Beckham fi ẹgbẹ́ agbabọ́ọ̀lu gbòógi lọ́lẹ̀ ni Miami

David Beckham fi ẹgbẹ́ agbabọ́ọ̀lu gbòógi lọ́lẹ̀ ni Miami Image copyright Matt Cardy
Àkọlé àwòrán "Mo seleri pe ẹgbẹ agbábọ́ọ̀lu naa yoo jẹ eyi to tayọ ju lọ"

Balogun nigbakan ri fun ẹgbẹ́ agbabọọlu orilẹede England, David Beckham ti se ifilọ́lẹ̀ ẹgbẹ́ agbabọọlu ti rẹ̀ lana nilu Miami lorilẹede Amẹrika.

Beckham lo anfaani to ni ninu iwe adehun iṣẹ́ to buwọ́lu pẹ̀lu ẹgbẹ agbabọọlu LA Galaxy lati ra ipin kan ninu eto imugbooro tẹgbẹ́ agbabọọlu naa se lọ́dun 2014.

Ẹgbẹ́ agbabọọlu rẹ̀ ọ̀hun ti wọn o ti sọ lorukọ ti setan lati gba bọ́ọ̀lu ni papa isere ẹlẹ́gbẹ̀run mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n eniyan to wa nilu Miami.

O ni "ínu mi dun lati se idasilẹ ẹgbẹ agbabọọlu nla yi - irinajo to lagbara pupọ̀ ni".

"Mo seleri pe ẹgbẹ agbábọ́ọ̀lu naa yoo jẹ eyi to tayọ ju lọ."

Fọ́nran fídíò kan safihan Beckham ati awọn ọmọ rẹ mẹ́rẹ̀ẹ́rin to fi mọ́ aya rẹ̀, Victoria. Awọn gbaju gbaja bi Serena Williams, Usain Bolt, Tom Brady to fi mọ́ Will smith, Jay Z ati Jennifer Lopez naa farahan ninu fídíò naa.

Image copyright Otto Greule Jr
Àkọlé àwòrán Beckham gba àmi ẹ̀yẹ orileede England marundinlaadọ́ta

Beckham to darapọ̀ mọ́ LA Galaxy lẹ́yin to kuro ni Real Madrid lọ́dun 2007, di agbabọọlu akọ́kọ́ ti yoo ni ẹgbẹ́ agbabọọlu ara rẹ̀ ninu gbogbo awọn to n kopa ninu liigi orileede Amẹrika.

Beckham to gbami ẹ̀yẹ orileede England marundinlaadọ́ta fẹ̀yinti gẹ́gẹ́ bi agbabọọlu lọdun 2013 lẹ́yin to lo oṣu máàrun pẹ̀lu Paris St-Germain yan an Miami lọdun naa gẹ́gẹ́ bi ibudo fun ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lu rẹ.

Ilu naa ko ni ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lu kankan lati igba ti Miami Fusion ti kogba wọle ni 2001.

Related Topics