Raila Odinga: Wọ̀n ó búra fún mi lónìí gẹ́gẹ́ bi àárẹ Kenya

Wọ́n ṣàpèjúwe ìgbésẹ̀ Odinga gẹ́gẹ́ bi ìdìtẹ̀ mọ́ ìjọba Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Wọ́n ṣàpèjúwe ìgbésẹ̀ Odinga gẹ́gẹ́ bi ìdìtẹ̀ mọ́ ìjọba

Olórí ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ní Kenya, Raila Odinga ti ní wọ́n o búra fún òun loni lai fi ti pe ó kùnà nínú ètò ìdìbò gbogboogbo tó wáyé lọ́dún tó kọjá ṣe.

Agbẹjọ́rò àgbà l'orileede Kenya ni igbésẹ̀ ìdìtẹ̀ mọ́jọba ni èròǹgbà nàá. Lórí èyí, iléèṣẹ́ ọlọ́páà ti gbé ibùdó tí ẹgbẹ́ òsèlú ọ̀gbẹ́ni Odinga, NASA ń gbèrò láti lò fún ètò nàá láàrin gbùn-gbùn ílu Nairobi.

Ẹ̀wẹ̀, àárẹ Uhuru Kenyatta ti kìlọ̀ fún àwọn iléèṣẹ́'ròyìn tó ń bẹ ní Kenya láti máà ṣàfihàn ètò nàá.

Wọ́n wọ́gi lé èsì ìbò gbogboogbò tó wáyé nínú oṣù kẹjọ, ọdún 2017 nítorí àwọn ẹ̀sùn àìṣe déèdé tó jẹyọ lẹ́yìn rẹ̀.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Wọ́n ṣàpèjúwe ìgbésẹ̀ Odinga gẹ́gẹ́ bi ìdìtẹ̀ mọ́ ìjọba

Àtúndì ìbò wáyé, ṣùgbọ́n ọ̀gbẹ́ni Odinga kọ̀ láti kópa, tí Kenyatta si jáwé olúborí.

Ogúnlọ́gọ̀ àwọn alátìlẹyìn ẹgbẹ́ alátakò làwọ́n ọlọ́páà ti ṣekúpa lásìkò ìwọ́de.