Ọpọlọpọ ẹmi sofo latari ikọlu awọn ọmọ ogun oju ofurufu

Image copyright Nigerian Airforce Official Site
Àkọlé àwòrán Ọmọ ogun Naijiria ko naani ẹmi awọn araalu

Ẹgbẹ ajafẹtọ awọn ti wọn ntẹ ẹtọ wọn loju mọlẹ, Amnesty International ti se atẹjade kan lori igbesẹ ti awọn alasẹ orilẹede Naijiria ngbe lati koju ikọlu to nwaye lawọn ilu igberiko.

Lonii, ẹgbẹ Amnesty International sọ wipe ninu osu kini ọdun 2018 nikan, ikọlu laarin awọn Fulani daran daran atawọn agbẹ ni ipinlẹ marun ti fa iku eniyan mejidinlọgọjọ.

Ipinlẹ Adamawa, Benue, Taraba, Ondo ati Kaduna ti foju ri ọpọlọpọ idamu ni osu diẹ sẹyin pẹlu wahala awọn agbẹ atawọn Fulani daran daran to nru soke di gbọnmi sii omi o to o ni gbogbo igba.

Ni ọjọ kẹrin osu kejila, ọdun to kọja, ile isẹ ogun oju ofurufu orilẹede Naijiria ran awọn ọkọ ija baalu lati fi ina ja ninu afẹfẹ lori awọn ilu kọọkan gẹgẹ bi ikilọ fun ikọlu to ma nwaye nigbati awọn daran daran kọlu o kere tan, ilu marun ni ipinlẹ Adamawa lati gbẹsan iku ara ilu wọn mọkanlelaadọta losu to kọja to jẹ wipe ọmọde lo pọ ju ninu wọn.

Image copyright @amnesty
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ ajafẹtọ ẹni, Amnesty International bu ẹnu atẹ lu igbesẹ awọn ọmọ ogun Naijiria

Nigbati ikọ Amnesty se ibẹwo si awọn ilu naa lẹyin fifi ina dẹru bolẹ ti awọn ọmọ ogun se lati oju ofurufu, wọn gbọ latẹnu awọn araalu to sapejuwe bi wọn se gbiyanju lati ba ẹsẹ wọn sọrọ nigba idẹru bolẹ ọhun.

Iwadii fihan wipe apapọ ikọlu awọn daran daran ati ti awọn ọmọ ogun oju ofurufu fa ijamba pupọ to bẹẹ to jẹ wipe o kere tan, ilu mẹjọ lo ni adanu nla tabi ka ni ina run awọn ilu naa yaan-yaan.

Osai Ojigho sọ wipe "iru ipa ti wọn lo fi se idẹrubalẹ yii buru jai, o nseku pani ko si ba ofin mu. O fihan wipe awọn ọmọ ogun Naijiria ko naani ẹmi awọn to yẹ ki wọn maa da abo bo. Ijọba gbudọ wa wọrọkọ fi s'ada lori ọrọ yii.

O sọ siwaju sii pe "ọpọlọpọ ẹmi lo nu lọdun to kọja ti ijọba ko si se ohunkohun to to lati da abo bo awọn ilu to ri ikọlu nitori ohun to buru ni pe awọn to nse ikọlu yii kan nlọ lọwọ ofo ni. Bẹẹ si ni iru ọwọ ti awọn ọmọ ogun naa ngbe tun nfa iku sii ni.

Ẹwẹ, alukoro ile isẹ ogun oju ofurufu, ọgagun Olatokunbọ Adesanya sapejuwe ija inu ofurufu naa gẹgẹ bi "ibọn fun ikilọ, kii se fun ipaniyan. O ni wọn ta awọn eniyan lolobo lati sa asala fun ẹmi wọn ni eyi to si ni ipa rere".

Lẹyin ọsẹ meji ti isẹlẹ yii waye, Adesanya sọ wipe awọn daran daran naa doju ija ibọn kọ ọkọ baalu ti awọn ọmọ ogun fi nsisẹ ti wọn si ni fidio gbogbo eyi.

Ẹgbẹ Amnesty International wa funpe si awọn ọmọ ogun oju ofurufu (ti wọn ti gba ikọni to to latọdọ awọn ọmọ ogun orilẹede UK ati ilẹ Amẹrika) lati jọwọ fidio ti wọn ni yii ati gbogbo irooyin ti wọn ba ni fun awọn alasẹ, to fi mọ adajọ agba orilẹede Naijiria ati minisita fun ọrọ abo fun iwadii.