Ahmed Musa: CSKA Moscow tọwọ bọwe lati ya atamatase Leicester City

Aworan Ahmed Musa ati Claudio Ranieri Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Olukọni fun ẹgbẹ Leicester nigba kan ri Claudio Ranieri lo ra Musa sinu ẹgbẹ agbabọọlu naa

Wọn ti ya atamatase agbabọọlu ikọ Leicester City, Ahmed Musa lọ si ikọ agbabọọlu CSKA Moscow titi di ipari saa bọọlu ọdun yii.

Wọn ra ọmọ ọdun mẹẹdọgbọn orilẹẹde ọhun lati CSKA lọdun 2016 fun milliọnu mẹrindinlogun pọun wa si Leicester fun adehun ọlọdun mẹrin.

Sugbọn nise ni o'n tiraka lati fẹsẹ rinlẹ ninu ẹgbẹ agbabọọlu naa.

Ẹmaru-un pere lo ri bọọlu gba wọnu awọn ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹtalelọgbọn.

CSKA sọ wi pẹ Musa yoo kopa ninu ifesewonse ninu idije li ati ipele komeseoyo liigi Europa.