Raila Odinga ti se ibura wọle fun 'rarẹ gẹgẹ bi aarẹ

Raila Odinga fi bibeli bura Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Olori ẹgbẹ alatako, Raila Odinga gba ibura sipo gẹgẹ bi aarẹ ara ilu

Olori alatako nilu Kenya,Raila Odinga,ti gba ibura wole sipo gẹgẹ́ bi ''Aarẹ ara ilu'' ni itako asẹ ijọba to ni igbese bee jẹ ifi'te gbajoba.

Ogbeni Odinga gba ibura oun nigba ti o di bibeli alawo ewe dani ni iwaju ogunlọgo awọn alatilẹhin re ni papa igbafe Uhuru ni Nairobi, olu ilu ilẹ Kenya.

Awọn ọmọ orilẹẹde Kenya ati awọn ọmọ ile Afrika ti'n dasi ọrọ naa lori Twita.