Ileẹjọ ka EFCC lọwọ ko lori iwadi isuna awọn ipinlẹ

Eniyan to nka owo Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idajọ ileẹjọ lee mu ekuru gba ẹyin ni ifanfa fun ajọ EFCC

Ileẹjọ giga apapọ kan nilu Ado Ekiti ti gbe idajọ kalẹ wipe ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria, EFCC ko lẹtọ labẹ ofin lati tan ina wadi isuna tabi inawo awọn ipinlẹ.

Ileẹjọ giga apapọ naa gbe idajọ yii kalẹ lọjọ isẹgun, to si sọọ di mimọ wipe ileegbimọ asofin ipinlẹ nikan ni ofin ilẹ Naijiria faaye gba lati ti oju bọ inawọ ati isuna ipinlẹ koowa wọn.

Idajọ yii ko sẹyin ẹjọ ti ijọba ipinlẹ Ekiti nipasẹ agbẹjọrọ agba nibẹ pe ajọ EFCC atawọn mẹtadinlogun miran lori bi o se gbe ẹsẹ le asuwọn owo ijọba ipinlẹ ọhun.

Onidajọ Taiwo Taiwo to gbe idajọ naa kalẹ nii, labẹ isejọba tiwa-n-tiwa, ijọba apapọ kii se alamojuto awọn ẹka isejọba yooku bẹẹni kii se atọna isuna wọn.

Pẹlu eyi, ile ejọ ti wa ka ajọ ọhun lọwọ ko wipe ki o yee ti oju bọ isuna ipinlẹ Ekiti yala nipa sise iwadii iwe isuna rẹ ni tabi fifi ofin gbe osisẹ yoowu to ba jẹ ti ipinlẹ naa.

Nigba to n sọrọ lori ikanni ayelujara Twitter rẹ, gomina ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayose ni oun ko ni yee ja fun ifẹsẹmulẹ isejọba awarawa lorilẹede Naijiria.

Àwọn ojú òpó ayélujára tí ó jọ èyí

BBC kò mọ̀ nípa àwọn nnkan tí ó wà nínú àwọn ojú òpó ayélujára ní ìta