Ile asofin agba si ọmọ Naijiria: Ẹ sọra fun owo bitcoin

owo ori afẹfẹ Bitcoin Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Awọn asofin agba ilẹ Naijria nfẹ ipolongo lori ewu to nbẹ ninu idokoowo owo ori afẹfẹ Bitcoin

Ileegbimọ asofin agba lorilẹede Naijiria ti ke gbajare sita wipe ki awọn araalu sọra fun owo ori afẹfẹ, Bitcoin eleyi ti wọn sọ pe o ti n di tọrọ fọnkale bayii.

Eyi kun ara awọn afẹnuko awọn asofin agba orilẹede Naijiria nibi ijoko wọn ni ọjọ isẹgun.

Wọn ni bi awọn ọmọ orilẹede Naijiria se n bẹ gija sinu idokoowo owo inu afẹfẹ bit-coin n pe fun amojuto to peye.

Nigba to n lewaju aba lori rẹ, sẹnatọ Benjamin Uwajumogu ni o se pataki ki ile tete mojuto ọrọ naa ki o to di eyi ti yoo tun ran pupọ ọmọ ilẹ Naijria lọ si oko gbese bii ti awọn to saaju rẹ.

Lẹyin ọpọlọpọ ijiroro, awọn asofin agba duro lori ifẹnuko mẹta ọtọọtọ ninu eyi ti wọn ke si banki apapọ ilẹ Naijiria pẹlu ileese alaabo oludokoowo ilẹ Naijiria, NDIC pẹlu ileesẹ ọja idokoowo ilẹ Naijiria, NSE lati dide giri si ọrọ naa ki wọn si tete fọn rere ewu to mbẹ ninu idokoowo owo inu afẹfẹ bitcoin fun awọn araalu.

Bakan naa ni wọn tun ke si ajọ ilanilọyẹ lorilẹede Naijiria, NOA lati polongo faraalu ki wọn si rọọ ko-ko-ko bi ifa aditi fun awọn eniyan wipe ara awọn banki sogundogoji ni idokoowo naa jẹ.

Related Topics