Ọlọpa:Ọwọ palaba adigunjale mẹrin segi nipinlẹ Ọsun

Awọn ọkọ ti awọn ọlọsa naa ji gbe Image copyright Baba Oloye
Àkọlé àwòrán Ọpọ araalu lo ti padanu ọkọ wọn si ọwọ awọn ọlọsa ti ọwọ ba yii

Ọkọ ayọkẹlẹ mọkandinlogun lawọn ọlọpa ti gba lọwọ awọn adigunjale nipinlẹ Ọsun.

Awọn ọlọpa ni ọwọ palaba awọn igara ọlọsa mẹrin naa, ti wọn ti nfi oju awọn eeyan ipinlẹ ọhun han eemọ fun igba di segi nitori isẹ iwadi ijinlẹ ati ọtẹlẹmuyẹ to yaranti.

Kọmisọna ọlọpa npinlẹ Ọsun, ọgbẹni Fimihan Adeoye ni, gbogbo awọn afunrasi ti ọwọ ba naa, ni wọn ti fi igbakan ri sa lọgba ẹwọn ki wọn to tun jade pada si ẹnu isẹ alọkolounkigbe ti wọn yan laayo.

Image copyright Baba Oloye
Àkọlé àwòrán Ileesẹ ọlọpa ni gbogbo awọn ọbayejẹ lọwọ yoo ba nipinlẹ ọsun laipẹ

Kọmisọna ọlọpa Adeoye ni, awọn ọlọpa yoo se iwadi to jinlẹ lori ọrọ wọn, yoo si rii daju pe wọn ko bọ lọwọ ofin.

Gbogbo ọkọ ti wọn gba lọwọ awọn afunrasi ọhun lo jẹ ayọkẹlẹ, ti wọn gba kaakiri tibu toro ipinlẹ Ọsun.

Ọga ọlọpa nipinlẹ Ọsun tun fi kun-un wipe, ileesẹ ọlọpa ti n se eto ilana tuntun fun igbogunti iwa ọdaran nipinlẹ naa, eyi to ni yoo wa egbo dẹkun fun gbogbo iwa awọn kọlọransi lawujọ nibẹ.