George Weah ge owo osu rẹ gẹgẹbi aarẹ Liberia

Aarẹ George Weah ti orilẹede Liberia Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Ofin ẹlẹyamẹya ni ofin to tako awọn ajoji lati ni ile lorilẹede Liberia

Aarẹ tuntun lorilẹede Liberia, George Weah ti jẹjẹ lati ge owo osu rẹ walẹ fun saa kan, eyi ti yoo da gba inu apo asunwọn owo idagbasoke lọ, ti yoo si tun faaye gba kawọn ọmọ ilẹ okeere maa ni ile lorilẹede naa.

Aarẹ Weah kede eyi lasiko to n bawọn ọmọ orilẹede Liberia sọrọ nibi to ti sin wọn ni gbẹrẹ ipakọ pe sanmọni yoo lọ tinrin fun wọn nitori pe ojojo owo nse orilẹede naa.

"Ipo ọrọ aje tijọba mi jogun nsọ fun wa pe isẹ pọ lati se, taa si tun gbọdọ gbe ọpọ ipinnu kalẹ pẹlu.Ọda owo n ba wa finra, agbara owo orilẹede wa ti dinku, ti awọn ọja si gbe owo gege lori."

Àkọlé àwòrán Ọrọ aje orilẹede Liberia nla akoko to le kọja

Bakanaa ni Weah seleri lati gbogun ti iwa ajẹbanu eyi to dun mọ awọn ọmọ orilẹede naa ninu.

"Nitori ojojo to n se ogun ọrọ aje orilẹede wa, mo n sọ fun yin pe lati akoko yi lọ, ma se adinku owo osu ati ajẹmọnu mi pẹlu ida mẹẹdọgbọn, ti maa si ko sinu apo asunwọn owo idagbasoke orilẹede Liberia."

Awọn ajoji yoo bẹrẹ si ni di onile lorilẹede Liberia.

Bakanaa, Aarẹ Weah sapejuwe abala ofin to ni "awọn alawọ dudu nikan" lo lee ni ilẹ lorilẹede Liberia gẹgẹbi eyi ti ko tọ, iwa ẹlẹyamẹya ati ofin ti ko nitumọ.

O fikun pe, oun yoo se atunse ofin naa lati ri daju pe ẹnikẹni to ba beere lati jẹ ọmọ ilẹ Liberia atawọn ọmọ ilẹ okeere di baba onile lorilẹede Liberia.