Ile-isẹ ifowopamọ apapọ n yọ owo ayọju - Magnus Abe

Ile-isẹ ifowopamọ apapọ lorilẹede Naijiria, (CBN) Image copyright @cenbankng
Àkọlé àwòrán Ile igbimọ asofin nwa ọnọ abayo si idojukọ awọn oludokowo

Ile igbimọ asofin agba ti gba lati se iwadi lori bi Ile-isẹ ifowopamọ apapọ lorilẹede Naijiria, (CBN) se n yọ owo lọnọ aitọ ni apo asuwọn awọn onibara ni ẹka banki ifowopamọsi.

Aba yi ko sẹyin bi asofin agba, Magnus Abe ati awọn mejilelogun miran, se gbe ọrọ naa ka'lẹ, gẹgẹ bi ọrọ pajawiri, lati se ofintoto lori bi ile-isẹ ifowopamọ apapọ se n yọ owo layọju ati lọnọ aitọ lọwọ awọn eniyan.

Ọkan lara awọn asofin agba naa parọwa si ijọba apapọ lati daabobo ẹtọ awọn ọmọ Naijiria, lori yiyọ owo aitọ ni apo asuwọn wọn. Asofin naa wipe ti wọn ba se eyi, yoo da eto ifowopamọ orilẹede yi pada s'ipo.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ile Igbimọ asofin yoo se'wadi Banki apapọ lori idiyele owo ti ko t'ọnọ

Awọn asofin naa faramọ wipe ki wọn se ijiroro ita gbangba pẹlu awọn alakoso ile-isẹ ifowopamọ to wa lorilẹede Naijiria, to fi mọ Gomina banki apapọ, Gọdwin Emefiele.

Ile igbimọ asofin agba ni igbagbo wipe ijiroro itagbangba naa yoo wa ọnọ abayo si idojukọ awọn oludokowo pẹlu awọn ile-isẹ ifowopamọ gbogbo.