LCC fikun owo ẹnu ibode Ikoyi, Lekki nilu Eko

Ẹnu ibode Lekki Image copyright @LCCTollRoad
Àkọlé àwòrán LCC sọ pe gbogbo nnkan ti gb'owo lori ni Naijiria

Ile isẹ Lekki Concession Company Limited, LCC ti kede afikun owo ẹnu ibode Lekki ati oke afara Ikoyi lati ọjọ kini, osu keji ọdun yi.

Ile-isẹ LCC ninu atẹjade fun awọn akọroyin sọ wipe, ifikun owo ẹnu ibode naa, ko sẹyin bi ọrọ aje ilẹ Naijiria se d'ẹnukọlẹ, eleyi ti o mu ki iye owo ti wọn fi tun agbegbe naa se lọ s'oke ju ti tẹlẹ lọ.

Adari fun ile isẹ naa, Mohammed Hassan sọ pe igbesẹ naa waye lẹyin ijiroro ti wọn se pẹlu awọn alẹnulọrọ agbegbe Eti-Osa pẹlu popona Lẹkki-Ẹpẹ n'ilu Eko, lọdun ti o kọja

Image copyright @LCCTollRoad
Àkọlé àwòrán Ijọba ipinlẹ Eko fofin de ifikun iye owo ẹnu ibode Lẹkki si Ẹpẹ

Hassan wi pe awọn awakọ elero ati kẹkẹ yoo maa san ọgọrun naira to yatọ si ọgọrin naira ti wọn n san tẹlẹ, sugbọn awọn to ni ami idanimọ yoo san aadọrun naira.

Awọn ọlọkọ bẹnbẹ yoo san iye owo toto igba naira si irinwo naira, nigba ti awọn ọkọ nla nla yoo san irinwo naira ati bẹẹbẹẹlọ.

Ti a ko ba gbagbe, lọjọ karun, osu kejila ọdun ti o kọja, ni ijọba ipinlẹ Eko fofin de ifikun iye owo ẹnu ibode Lẹkki si Ẹpẹ.