EPL: Asise rẹpẹtẹ s'okunfa ifidirẹmi fun Arsenal

asọle Arsenal Petr Cech l'ojule Image copyright AFP/GETTY IMAGES
Àkọlé àwòrán Sam Clucas gba ami ayo meji wọle ninu idije ti asọle Arsenal Petr Cech ti se asise l'ojule

Asise Petr Cech ti o jẹ asọle fun ẹgbẹ Arsenal nigba ti wọn wọ'ya ija pẹlu Swansea nibi ti wọn ti fidi rẹmi pẹlu ami ayo mẹta si ẹyọ kan lalẹ ọjọ isẹgun.

Ọmọ agbabọọlu Swansea Jordan Ayew f'agba han Cech loju'le nigbati ti o gba amin ayo kan wọle. Eyi jẹ ikunọ fun ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal lẹyin ti Sam Clucas ti gba ami ayo meji s'ojule.

Ikọ Arsenal bi jabọ si ipo kẹfa lori tabili liigi, ti wọn to s'ẹhin ikọ Liverpool ti o wa ni ipo kẹrin.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ikọ Arsenal bi jabọ si ipo kẹfa lori tabili liigi, ti wọn to s'ẹhin ikọ Liverpool ti o wa ni ipo kẹrin

Akọni-mọọgba fun ẹgbẹ Arsenal, Arsene Wenger ti salaye wipe awọn asise ti awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal se lori papa lo se okunfa ijakulẹ ninu idije naa. O wi siwaju sii pe loni ni awọn yoo mọ nipa boya ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Borrusia Dortmund, Pierre-Emerick Aubameyang yoo darapọ mọ wọn tabi bẹẹkọ.

Related Topics