Olamide Baddosneh ṣe ìdárò ìyá rẹ̀ tó d'olóògbe

Ikú ìyá nàá ṣe kòǹgẹ́ ọjọ́ ìbí ọmọ rẹ̀ Image copyright Baddosneh/Instagram
Àkọlé àwòrán Ikú ìyá nàá ṣe kòǹgẹ́ ọjọ́ ìbí ọmọ rẹ̀

Gbajú gbajà akọ̀rin tàkasúùfe, Olamide tí gbogbo èéyàn mọ̀ sí Baddosneh pàdánù ìyá rẹ̀ lánàá.

Ikú ìyá nàá ṣe pẹ̀kí ǹ pẹ̀kí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọmọ Olamide tó kò lánàá.

Baddosneh kéde ìṣẹ̀lẹ̀ tó ba ni lọ̀kàn jẹ́ ọ̀hún lójú òpó ìbánidọ́rẹ́ẹ̀ Instagram rẹ̀ lana pẹ̀lú àkòrí "Orisa bi Iya o si".

Olamide àti DJ Enimoney lo àwòrán dúdú lójú òpó Instragram wọn láti ṣe ìdárò ìyá wọn.

Awọn ọ̀rẹ́, tó fi mọ́ alájọṣiṣẹ́pọ̀ àti olólùfẹ́ rẹ̀ ti ń ránṣẹ́ ìbánikẹ́dùn si i, ti wọ́n si n gbadùrà pe Ọlọrun yòó dúró ti i.

Ọmọ mẹ́ta ló gbẹ̀yìn ìyá nàá; Olamide tó fi mọ́ ẹ́gbọ́n rẹ̀ obìnrin àti DJ Enimoney.