Ọbasanjọ se amusẹ ifilọlẹ ẹgbẹ alajumse

Olusegun Obasanjo
Àkọlé àwòrán Ala Ọ́basanjọ lati sedasilẹ ẹgbẹ alajumọse ti dohun

Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ọsun, Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla ti sefilọlẹ agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ọmọ Naijiria nilu Abuja, to si ni jakumọ ni oun, oun kii se ẹran ilu kan, ko si sẹgbẹ oselu kankan to lee so oun mọlẹ.

Ọmọọba Oyinlọla ni iyatọ wa ninu ki eeyan jẹ ọmọ ẹgbẹ oselu ati ko faramọ ẹgbẹ ajumọse lasan nitori naa, oun si jẹ ọmọ ẹgbẹ oselu APC.

"A gbọdọ se kankan lati ri daju pe ẹgbẹ ajumọse awọn ọmọ orilẹede yi naa na iyẹ ka tibu tooro Naijiria ni kiakia nitori ko si akoko fun wa mọ, eyiun taa ba fẹ ki awọn afojusun wa jọ".

Ọmọọba Oyinlọla ni lara afojusun ẹgbẹ ajumọse naa ni lati se amusẹ ilakaka wọn, eyi tii se igbesẹ gbigbe ipo asaaju Naijiria le awọn ọdọ to loye, ti musemuse wọn si da musemuse lọwọ.

Oniruuru awọn iwe iroyin si lo ti gbe orisirisi iroyin sita nipa ifilọlẹ ẹgbẹ alajumọse naa.

O ni ojuse awọn agbaagba to wa ninu ẹgbẹ alajumọse naa ni lati maa jẹ atọna fawọn ọdọ ninu ẹgbẹ naa, tawọn ọdọ yoo si duro bii awakọ ti yoo maa dari ọkọ Naijiria loju agbami oselu.

"Awọn ẹgbẹ oseluAPC ati PDP ko kaato to lati ba aini awọn smọ orilẹede yi pade, idi si niyi to fi yẹ ka se agbeyẹwo ara wa, ka lee tẹsiwaju."

Awọn agbaagba ni yoo maa satọna fawọn ọdọ ninu ẹgbẹ alajumọse

Yatọ sawọn ogulọgọ ọdọ to peju sibi ifilọlẹ ẹgbẹ alajumọse naa, lara awọn eekan ọmọ orilẹede yi mii to tun bawọn peju sibẹ ni alaga tẹlẹ fẹgbẹ oselu PDP, Amadu Alli, ati Akin Ọsuntokun tii se agbẹnusọ fun oloye Ọbasanjọ nigba to fi wa lori aleefa bii aarẹ Naijiria.