Ọlọpa kan yinbọn mọ ọga rẹ nitori obinrin nipinlẹ Adamawa

Ọlọpa ilẹNaijiria Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ogogoro boju ọlọpa kan to fi yinbọn m ekeji rẹ

Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpa ipinlẹ Adamawa, Othman Abubakar, ti fidi rẹ mulẹ pe ẹmi ọlọpa kan ti bọ sinu ede aiyede kan to bẹ silẹ laarin ọlọpa meji.

Ile ọti kan to wa nijọba ibilẹ Madagali si ni isẹlẹ naa ti waye.

Ẹnikan ti isẹlẹ naa soju rẹ ti salaye pe obinrin kan to n ta ọti lo sokunfa ija awọn ọlapa mejeeji yi, ẹni to tun jẹ ọrẹbinrin ọkan lara awọn ọlọpa naa.

"Awọn mejeeji tutọ si ara wọn loju lori obinrin naa to jẹ ọrẹbinrin Kọburu Adamu lalẹ ọjọ isẹgun.Obinrin ọlọti yi si lo fẹjọ sun Adamu pe Sajẹnti Timothy ko sanwo ọti to mu eyi tii se ọgarun naira."

"Timothy yi lo ti kọkọ mu ife ọti ogogoro kan lai sanwo, to si tun fk gba omii si. Amọ Adamu lo kilọ fun pe ko sọra nipa awọn gbolohun to n jade lẹnu rẹ si ọrẹbinrin oun, bibẹẹkọ, oun yoo fi imu rẹ darin."

Lootọlootọ ni Kọburu Adamu ba ki ibọn rẹ, to si yin mọ Sajẹnti Timothy, to si paa loju ẹsẹ, lọrọ ba di boolọ, koo yago fun mi.