Maiduguri: Ẹmi marun s'ofo ninu ibugbamu ado oloro n'ibugbe ifiniwọsi

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Awọn agbesunmọmi pa ogunlgọ eniyan nilu Maiduguri nipinlẹ Borno

Iroyin wipe o to eniyan marun ti o ti padanu ẹmi wọn, ti mọkandinlogoji si farapa ninu ikọlu awọn agbesunmọmi ti wọn so ado oloro m'ọra ni ibudo ifiniwọsi ni ilu Maiduguri, ni ipinlẹ Borno.

Awọn osisẹ ile isẹ pajawiri (Sema) ti wọn fi idi ọrọ na mulẹ fun awọn oniroyin n'ilu Maiduguri, sọ wipe akọlu naa waye ni dede agogo mẹjọ alẹ ni ọjọru.

Alaga ile-isẹ Sema in Borno, Satomi Ahmed sọ wipe ọmọbinrin ẹsin okọku meji ni o wa sọsẹ naa ni agbegbe Dalori to sun'mọ ile eko giga fasiti ti Maiduguri.

Iroyin fi lede wipe ibugbe ifiniwọsi to wa ni Dalori nii o tobi julọ ni Maiduguri.

Amọ, awon ọlọpa ati ile-isẹ ọmọogun Naijiria ko tii s'ọrọ nipa isẹlẹ yi.