Ipaniyan Benue: Ijọba kede isede lati agogo mẹfa irọlẹ si mẹfa idaji

Gomina Samuel Ortom Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Gomina Benue gbe asẹ isede kalẹ

Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom ti fasẹ si ofin isede k'onile o gbe'le lati alẹ si kutukutu owurọ ni ilu Gboko nipinlẹ Benue.

Oludamọran pataki fun Gominọ lori ọrọ Iroyin, Tahav Agerzua ninu atẹjade sọ wipe ofin yi yoo wa titi di ọjọ iwaju.

Agerzua ni asẹ k'onile o gbe'le naa yoo wa lati agogo mẹfa irọlẹ si agogo mẹfa owurọ lojojumọ lati le koju iwa ipaniyan agbegbe naa.

Gomina Ortom wa parọwa si awọn ara agbegbe Gboko lati faramọ ofin k'onile o gbe'le naa, ki alafia o le jọba lagbegbe naa.

Ti a ko ba gbagbe, ija abẹle ni awọn igberiko agbegbe naa ti sekupa ọgọrun eniyan, ti ijọba ipinlẹ naa si wipe awọn ti sin eniyan mejilelaadọrin si iboji tuntun to wa ni Makurdi, lọjọ kejila, osu kini, ọdun yi.

Related Topics