EPL: Chelsea ati Manchester United f'idi rẹ'mi

Agbabọọlu Manchester United lori papa pelu Tottenham Hotspur Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Manchester United wa ni ipo keji lori tabili pelu ami mẹ́tàleláàdọ́ta

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ati Chelsea ti ja walẹ kuro loke tente ti wọn wa lori tabili ife eye Premier League latari bi wọn se f'idi rẹ'mi ninu ifẹsẹwọnsẹ pelu Tottenham Hotspur ati AFC Bournemonth lalẹ ọjọru.

Tottenham na awọn ọmọlẹyin Jose Mourinho pẹlu ami ayo meji si odo ni papa isere Wembley, bẹẹni awọn ikọ agbabọọlu Bournemonth fi'ya jẹ Chelsea pẹlu ami ayo mẹta si odo ni papa isere Standford Bridge.

Christian Eriksen gba bọọlu sinu awọn lẹyin isẹju mọkanla, ti Tottenham pẹlu ami ayo meji sodo f'opin si bi o se si ẹgbẹ agbabọọlu kankan to na ikọ Manchester United ni saa yi.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Chelsea wa ni ipo kẹrin pẹlu ami àádọ́ta

Ọmọ ikọ Bournemouth, Callum Wilson lo kọkọ gba bọọlu s'inu awọn ni gẹrẹ ti wọn bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ naa ni papa isere Standford Bridge, ki o too di wipe wọn bori Chelsea ninu ifẹsẹwọnsẹ naa pẹlu ami ayo mẹta si odo.

Lọnọ miran ẹwẹ, Manchester City nọ Westbrom pẹlu ami ayo mẹta s'odo, eyi ti o gbe wọn soke tente tabili Premier League pẹlu ami méjídínláàdọ́rin.