Kenya: Ile isẹ amohunmaworan mẹta yoo wa ni titi latari "iburawọle" Odinga

Aworan ile ile amohunmaworan kan ti won tipa ni Kenya Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ile isẹ amohunmaworan mẹta yoo wa ni titi latari "iburawọle" Odinga

Ile-isẹ amohunmaworan mẹta to tobijulọ ni orilẹede Kenya yoo wa ni titi nitori igbiyanju wọn lati safihan eto iburawọle lori afefe fun adari alakato to se ibura fun ara rẹ gẹgẹbi aarẹ orilẹede naa ni Nairobi.

Minister f'ọrọ abele ni Kenya, Fred Matiang ti o sọrọ yin fun awọn oniroyin, wipe awọn ile-isẹ amohunmaworan naa yoo wa ni titi d'igba ti awọn yoo fi pari iwadi.

Ile-isẹ naa ninu atẹjade lori ẹrọ ayelujara sọ wi pe gbigbe ayẹyẹ iburawọle naa sori afẹfẹ jasi ipadiapopọ lati gba'jọba lọwọ aarẹ Uhuru Kenyatta, eleyi ti wọn sọ pe o le jasi iku ọpọlọpọ awọn ọmọ orilẹede Kenya.

Image copyright KTN
Àkọlé àwòrán Ajọ awọn oniroyin nilẹ Kenya, sọ pe igbese ijọba Kenya naa kọjumọ, ti kosi lẹtọ labẹ ofin to faaye gba ominira awọn oniroyin

Nitori naa, ni wọn se gbe NTV, KTN ati Citizen TV kuro lori afẹfẹ lagoogo mẹsan kọja isẹju mẹwa, (niye aago Kenya), lọjọ ibura naa.

Ninu ọrọ tiwọn, ajọ awọn oniroyin nilẹ Kenya, sọ pe igbese ijọba Kenya naa kọjumọ, ti kosi lẹtọ labẹ ofin to faaye gba ominira awọn oniroyin.

Ninu atẹjade ti wọn naa, awọn ẹgbe oniroyin naa pe fun ibọwọ fun ofin orilẹede naa ati opin si idukoko mọ awọn oniroyin ni Kenya.

Ajọ to n se ilana awọn oniroyin, (Media Council of Kenya) sapejuwe isele naa gẹgẹ bi iwa idukoko tikolafiwe, eleyi ti wọn so pe ko yẹ ko waye ni ijọba tiwantiwa.

Amọ, Minisita fọrọ abele orilẹede naa wipe, isẹ awọn ile-isẹ amohunmaworan naa tapa si ofin to de aabo orilẹede naa.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Tom Kajwang ti wa ni ihamo ijoba leyin iburafuni yii

Wẹrẹ ti Minista yi fọrọ yi lede ni wọn fi panpẹ ọba mu asofin fun ẹgbẹ alatako, MP Tom Kajwang ti o ko'pa to pọju ninu ayẹyẹ to fi Raila Odinga jẹ "Aarẹ awọn eniyan".

Kajwang ti o jẹ ọkan poogi lara awọn alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ alatako naa, lo wọ asọ adajọ agba to bura wọ'le fun Odinga nibi ayẹyẹ naa, ti ọpọ alatilẹyin ẹgbẹ alatako na si ba Odinga yọ lori ibura to waye ni Uhuru park ni olu-ilu Kenya, Nairobi.

Amọ, ko i ti di mimọ iru ẹsun ti wọn yoo fi kan Kajwang naa.

Ọgbẹni Odinga se ibura wọ'le fun ara rẹ lẹyin ti o wipe ohun ni awọn eniyan dibo fun gege bi aarẹ orilẹede naa ninu idibo sipo aarẹ lọdun to kọja.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIburafuni waye fun Odinga leyin awuye-wuye lori eto idibo

Ti a ko ba gbagbe, wọn se ibura fun aarẹ Uhuru Kenyeta fun saa keji, losu kọkanla ọdun ti o kọja. Aarẹ Kenyetta bori ninu atundi idibo to waye losu kẹwa, sugbọn ọgbẹni odinga ko kopa ninu idibo naa.

Related Topics