Facebook: Atunto tuntun se idinku awọn alamulo

Adari Facebook, Mark Zuckerberg nibi ti o ti n sọrọ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Adari Facebook, Mark Zuckerberg sọ pe dun 2017 gbona pupọ fun ile ise naa

Facebook ti sọ wi pe awọn to n samulo itakun ayelujara naa ti lọ silẹ ju tatẹyin wa lọ, lẹyin ti wọn se atunto miran ti yoo maa faaye silẹ fun awọn eniyan lati ri ohun ti awọn ibatan ati ọrẹ wọn ba fi sori itakun naa ju ipolongo lọ.

Itakun ayelujara naa ninu iroyin ti wọn fi lede wi pe, ayipada ti awọn se lori ipolongo ọja, ipolongo ẹgbẹ oselu lori itakun agbaye naa, jẹ ọna abayọ lati koju ipalara ti oni lori ọrọ awujọ.

Adaari agba ile-ise naa, Mark Zuberberg sọ wipe esi atunto naa se pere ju ohun ti wọn fojusọna fun ati wi pe atunse naa yoo ran itakun Facebook lọwọ lọjọ iwaju.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Facebook sọ wipe awọn eniya lo beere fun atunto opo ayelujara naa

Zukerberg to pe ọdun 2017 ni ọdun to lagbara julo ati eyi to tun le julọ, fikun un wi pe iye owo to wọle fun facebook lọdun to kọja ru gẹgẹ soke pẹlu ida mẹtadinlaadọta ninu ida ọgọrun ju tatẹyin wa pẹlu ere toto ida mẹrindinlọgọta.

O ni igbesẹ ti Facebook gbe lati din ifihan fidio to ba wọpọ kuru, ti jẹ ki ida marun awọn eniyan o lọra lati ma lo akoko to pọ loju itana Facebook.

Ni osu kini ọdun yi, itanna Facebook ni awọn yoo satunse bi awọn eniyan yoo se maa ri iroyin lori itakun naa, ati wipe awọn yoo jẹ ki awọn eniyan o maa ri nnkan ti ẹbi ati ọrẹ ba fi s'oju opo lọlọpọ ju ipongo awọn onisowo, ile-isẹ iroyin ati awọn ile-isẹ nlanla miran lọ.

Awọn onimọ nipa itakun agbaye ninu ọrọ wọn sọ wipe igbesẹ to dara ni Facebook gbe ati wipe yoo lapẹẹrẹ lọjọ iwaju.