CHAN: Super Eagles bori Sudan, gbaradi fun idije asekagba

Awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles Image copyright @NFF
Àkọlé àwòrán Eyi ni igba akọkọ ti Super Eagles yoo de idije asekagba CHAN

Naijiria ti n gbaradi fun idije asekagba ninu idije CHAN lẹyin ti wọn ti fagba han awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Sudan pẹlu ami ayo kan si odo nibi ifigagbaga Afirika ni ọjọru ni ilu Marrakech.

Naijiria yoo dojuko awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Morocco ninu asekagba idije lọjọ aiku nilu Casablanca.

Gabriel Okechukwu gba ami ayo kan wole fun Naijiria, eyi ti o ya awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu meji s'ọtọọtọ lẹyin iṣẹju mẹrindinlogun ti idije bẹrẹ.

Gbogbo akitiyan awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Sudan lati da ami ayo yi pada ja si pabo nitori pe awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles duro sinsin.

Image copyright @CAF_Online
Àkọlé àwòrán Gabriel Okechukwu jẹ ami ayo kan soso ninu idije yi

Awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Morocco gbe'gba oroke ninu ifagagbaga wọn pẹlu Libiya nigbati wọn bori pẹlu ami ayo mẹta si ẹyọ kan soso.

Sudan yoo pade Libya n'ibi idije asekagba fun awọn t'o f'idi rẹmi lọjọ abamẹta.

Related Topics