Ifilọlẹ ẹgbẹ alajumọse n waye n'ipinlẹ Ogun

Donald Duke, Olusegun Obasanjo ati Olagunsoye Oyinlola Image copyright Kazeem Olowe
Àkọlé àwòrán Ifilọlẹ agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ọmọ Naijiria ti waye nilu Abẹokuta

Ifilọlẹ agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ọmọ Naijiria n waye loni nilu Abẹokuta nipinlẹ Ogun.

Igbakeji alakoso eto ile-ìkàwé aare ana, (Olusegun Obasanjo Presidential Library), ọgbẹni Ayọdele Aderinwale sọ fun BBC Yoruba wi pe ifilọlẹ ile-isẹ isakoso fun agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ọmọ Naijiria (Coalition for Nigeria Movement) ni ile isẹ Iwe iroyin nilu Abeokuta.

Ni ọjọru, gomina tẹlẹ nipinlẹ Ọsun, Ọlagunsoye Oyinlọla se'filọlẹ agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ọmọ Naijiria nilu Abuja pẹlu awọn eniyan jankan-jankan nibẹ, ti wọn si n pe fun ifọwọsowọpọ agbajọ awọn mọ Naijiria fun idagbasoke ti o peye.

Bi orilẹede Naijiria se n sun'mọ asiko eto ipolongo idibo fun ọdun, orisirisi awọn ẹgbẹ oselu lo ti n jade lati polongo fun awọn eniyan lati kopa ti o peye ninu eto ijọba awarawa lorilẹede. Lara wọn ati awọn ti o n se alamojuto fun eto ifilọlọlẹ wọn ni:

Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ọmọ Naijiria (Coalition for Nigeria Movement)

Aarẹ Olusegun Ọbasanjọ

Ọlagunsoye Oyinlọla

Donald Duke

Ajọ idasi Isipopada Naijiria(Nigeria Intervention Movement):

Olisa Agbakoba

Charles Soludo

Pat Utomi

Yatọ sawọn ogulọgọ ọdọ to peju sibi awọn ifilọlẹ ẹgbẹ alajumọse wọnyi, awọn eekan ọmọ orilẹede yi miran ti n pe fun sise ifilọlẹ awọn ẹgbẹ oselu miran lati dopin aisedeede awọn ẹgbẹoselu APC ati PDP ti o ti wa ni ipo latẹyinwa.