West Ham: A ń ṣewádi ẹ̀sun dídẹ́yẹ si àwọn agbábọ̀ọ́lu tó jẹ́ ọmọ Áfíríkà

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ipò kejìlá ni West Ham wa nínú ìdíje Premier League

West Ham ti bẹ̀rẹ̀ iwadi lori ẹ̀sun ti wọ́n fi kan an pe ikan lara awọn osisẹ́ wọn sọ wipe ofin ẹgbẹ́ agbabọ́ọ̀lu naa ni lati ma gba agbabọ́ọ̀lu to jẹ́ ọmọ Afirika kan kan.

Iwe iroyin Daily Mail jàbọ̀ pe wọn sọ fun awọn pe West Ham ti dawọ́ gbigba àwọn agbabọ́ọ̀lu to jẹ́ ọmọ Afirika duro nitori wipe "wọ́n maa ń fa wàhálà ti wọn o bá ti sí lára ikọ̀ to ba lọ fun ìfẹsẹ̀wọn sẹ̀".

Àtẹ̀jáde kan láti ọwọ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà ni "ọwọ́ to lágbára la fi máà n mú àwọn ẹ̀sùn to jẹ mọ́ ẹlẹ́yàmẹyà".

"Ati n gbé ìgbésẹ̀ lati mọ òkodoro tó wà nini ẹ̀sùn náá."

Wọ́n fi kun pe gbogbo àwọn òṣìsẹ́ wọn lo gba idanilẹ́kọ to peye lori igbe aye iwọ o jùmí, èmi o jù ọ̀, to fi mọ́ ẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Àti wípé ìbọ̀wọ̀ funra ẹni wà ninu ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ́lu àwọn.

Agbábọ̀ọ́lu mẹ́fà to jẹ́ ọmọ Áfíríkà ni West Ham ni - Cheikhou Kouyate, Pedro Obiang, Joao Mario, Angelo Ogbonna, Arthur Masuaku and Edimilson Fernandes.

Atamátàsé fùn Senegal, Diafra Sakho kúrò nínú ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ́lu nàá lásìkò kátàkárà àwọn agbábọ̀ọ́lu tó wáyé lóṣù kìnní, tó si darapọ̀ mọ́ Rennes. Bakanna ni Andre Ayew lati orileede Ghana nàá lọ si Swansea.

West Ham ló wà ni ipò kejìlá nínú ìdíje Premier League, bótilẹ̀jẹ́ wípé pọ́intì mẹ́rin ló kù kí wọn o fi jáwálẹ̀ lórí tábìlì ìgbéléwọ̀n.

Ẹnìkan tó jẹ́ agbẹnusọ fun West Ham ni: "Ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ́lu yìí le fìdírẹ̀múlẹ̀ pe wọ́n ti fun olùdarí ẹ̀ka tó n gba àwọn agbábọ̀ọ́lu wọlé, Tony Henry níwe lọ gbéle ẹ titi ti iwadi yòó fi parí.

"West Ham o ni fi àáye gba ìwà ẹlẹ́yàmẹ̀yà kankan, nitori eyi, lo se gbe igbesẹ kiakia tori wipe awọn ẹ̀sun nàá lágbára."

"Ọkan ṣoṣo ni ẹbí West Ham, nibiti ẹnìkọ̀ọ́kan ti ṣe pàtàkì lọ́kúnrin tabi obìnrin láì fi ẹ̀yà, ọjọ́ orí, ẹ̀sìn ṣe."

"Ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ́lu yìí kò ni sọ ohun kóhun mọ́ títí tí ìwádí ì yóò fi parí."