Ileejọ Kenya wọgile ofin to ti ileesẹ tẹlifisan pa

Oniroyin KTN kan lori afefe Image copyright KTN
Àkọlé àwòrán Ajọ akoroyinjọ nilẹ Kenya sọ pe igbese ijọba Kenya naa ko bojumu, ti kosi lẹtọ labẹ ofin to faaye gba ominira awọn akọroyin

Ile ẹjọ giga lorilẹede Kenya ti wọgile asẹ ijọba, eyi to fi ti awọn ile isẹ amohunmaworan mẹta to tobi julọ lorilẹede naa pa.

Awọn ileesẹ agbohunsafẹfẹ yi ni wọn ti pinnu tẹlẹ lati gbe eto ibura olori awọn ọmọ ẹgbẹ alatako lorilẹede naa, Raila Odinga safẹfẹ lọjọ isẹgun.

Ile-ẹjọ giga naa sọ pe oun gbẹsẹle asẹ ijọba naa fun ọjọ mẹrinla ti igbẹjọ yoo fi waye lori ẹjọ naa.

Ọgbẹni Odinga lo fidi rẹmi ninu eto idibo lorilẹede Kenya lọdun to kọja,bẹẹ si ni ipinnu rẹ lati sebura fun ara rẹ loju taye gẹgẹbi olori orileede ọhun nijọba sọ pe o ta'pa si ofin, ti awọn alaṣẹ si ni o jẹ iwa iṣọtẹ sijọba.

Awọn ẹgbẹ oselu alatako si ti fi ẹsun kan ijọba orileede Kenya pe o lodi si ẹtọ ati ofin ilu.

Ti a ko ba gbagbe, wọn se ibura fun aarẹ Uhuru Kenyeta fun saa keji, losu kọkanla ọdun to kọja. Aarẹ Kenyettasi lo bori ninu atundi idibo to waye losu kẹwa, sugbọn ọgbẹni odinga ko kopa ninu idibo naa.

Akọroyin BBC nilu Nairobi, Ferdinard Omondi sọ pe, awọn ọmọ Kenya n binu lori bi wọn ko se lanfaani lati wo awọn iroyin ati awọn eto to wọn lori awọn ẹrọ amohunmaworan fun ọjọ kẹta ti wọn ti wa ni titipa.

Awọn ile-iṣẹ ti ofin naa kan ti padanu aimọye milionu dọla nipa aile gbohunsafẹfẹ won.

Ọgbẹni Omtata pe ẹjọ lati da'wọn pada sori afẹfẹ lẹsẹkẹsẹ ati fun ijọba lati sanwo ti wọn ipadanu gege bi owo itanran.

Related Topics