Iba ọrẹrẹ:Awọn asofin Naijiria yoo pese owo fun gbogun tii

Eku meji n jẹ eso Image copyright PA
Àkọlé àwòrán Fun asiko diẹ bayii ni awọn ọmọ Naijiria ti n ba arun iba Lassa finra

Pẹlu bi arun iba ọrẹrẹ se nse kẹrẹkẹrẹ tan kalẹ lawọn ipinlẹ kan lorilẹede Naijiria, ile asofin agba orilẹede yi ti seleri lati gbe ofin kalẹ fun ipese alekun owo fun gbigbogun ti arun ọhun.

Nibi ijoko ile to waye ni ọjọbọ lawọn asofin agba orilẹede yi ti fọwọ sọya lori igbesẹ lasiko ijiroro wọn.

Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Awọn asofin dide si ọrọ arun iba ọrẹrẹ lati wagbo dẹkun fun-un

Ni ilẹ to mọ loni yii, iroyin ti jẹ ko di mimọ wipe eeyan mọkanlelogun ni arun yi ti gbẹmi wọn, ti awọn miran to n lọ bi aadọta si wa ni idubulẹ arun naa.

Sugbọn awọn asofin agba ni gbọnmọgbọmọ arun iba ọrẹrẹ kii se ohun ti o bojumu, eyi ja si wipe omi nbẹ lamu fun awọn ileesẹ ati lajọlajọ ijọba gbogbo ti ọrọ kan lori arun iba ọrẹrẹ yii.

Kini awọn sẹnatọ kọọkan sọ lori kikoju aarun yii

"Fun ogoji ọdun ni a ti wa lẹnu ọrọ a n gbogunti arun iba Lassa . eyi fihan wipe iha kokanmi ni ileese eto ilera ijọba apapọ n kọ si ọrọ ọun."-Sẹnatọ Matthew Urhoghide.

"Ni nkan bii ọsẹ meji sẹyin, eeyan kan ku nipasẹ aarun yii. Ọrọ aarun yii nfẹ amojuto ni kiakia lati lee pinwọ ọwọja rẹ ko to de awọn ibi ti ko si tẹlẹ."- Sẹnatọ Ajayi Boroffice.

"A ni lati pada si orisun arun yii gan an ki a bẹrẹ igbesẹ kikoju rẹ nibẹ."-Sẹnatọ Matthew Urhoghide

Lara awọn sẹnatọ to da si ijiroro lori wahala arun iba ọrẹrẹ yi, ni wọn kọminu lori ọwọja arun iba ọrẹrẹ yi. Wọn ni o ti sọ ara rẹ di arọni mọ gbogbo orilẹede Naijiria lọwọ.

Image copyright @NCDCgov
Àkọlé àwòrán Ipinlẹ mẹtala ninu ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa ni orilẹede Naijiria ni aarun iba ọrẹrẹ ti de bayii

Bakanaa, awọn asofin agba orilẹede Naijiria tun ke si ileesẹ eto ilera ijọba apapọ nibẹ wipe ko tubọ jawe sobi lori igbesẹ gbogbo lati wa ọwọ arun naa wọlẹ.

Wọnni ohun ti ko see gbọ seti ni wipe ibudo kan soso lo wa lorilẹede Naijiria lati mojuto irufẹ awọn arun bayii to si tun jẹ wipe ibudo kan soso naa ko tun ni awọn ohun elo to kun oju iwọn lati se ojuse rẹ.

Image copyright @NCDCgov
Àkọlé àwòrán Ile asofin agba ni asiko to lati pese owo to jọju fun rira oogun ati ohun elo fun itọju aarun

Bakanna ni ile asofin tun ke si ajọ to nse kokaari isẹlẹ ajalu lorilẹede Naijiria wipe ko tete se abẹwo ojumitoo si awọn agbegbe ti arun yii ti nsọsẹ lati lee pese awọn ohun elo arẹmọlẹkun ti wọn nilo nibẹ fun wọn.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí