Ibrahim Idris: Ko gbọdọ si fijilante mọ ni Nigeria

Ọga ọlọpa Ibrahim Idris joko siwaju ọpọ ero Image copyright @PoliceNG
Àkọlé àwòrán Ọga ọlọpa Naijiria ni agbofinro nikan lo lẹtọ lati gbe ibọn.

Ọga agba patapata fun ileesẹ ọlọpa orilẹede Naijiria, Ibrahim Idris ti pasẹ fun awọn kọmisọna ọlọpa gbogbo lati rii daju pe wọn gba ohun ija gbogbo lọwọ awọn ikọ oju lalakan fi nsọri, ki wọn si tu wọn ka lẹyẹ-o-sọka.

Bakannaa ni ọga ọlọpa Idris tun pa aroko ikilọ ransẹ si awọn ijọba ipinlẹ gbogbo lati dẹkun iwa kiko ibọn ati ohun ija miran fun awọn ikọ ọmọgun kekeke labẹ iboju pe wọn n fl daabo bo ipinlẹ wọn.

O ni ko si abala ofin to fi aaye bẹẹ gba wọn lati se bẹẹ.

Ọga agba ọlọpa orilẹede Naijiria ni, awọn ileesẹ agbofinro nikan ni iwe ofin orilẹede yi fun lasẹ lati maa gbe ibọn.

Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọpọ ọmọ Naijiria lo n daabo bo ara wọn nitori ikọlu awọn darandaran Fulani

O wa fi kun un pe eyikeyi aletilapa to ba tapa si ofin yii labẹ boti wu kori, yoo fi imu ko ata ofin.

Ọga agba ọlọpa gbe asẹ yii kalẹ lasiko to n se ipade pẹlu awọn kọmisọna ọlọpa ipinlẹ ati awọn lọgalọga lẹnu isẹ ọlọpa.

Amọsa o, ọga ọlọpa, Ibrahim Idris ko sọrọ lori boya asẹ yii kan naa kan awọn darandaran fulani ti ọgọrọ awọn eeyan ti fi ẹsun pe wọn n gbe ohun ija oloro kiri, ti wọn si tun fi ẹsun sisekupa awọn eeyan kaakiri orilẹede yi kan wọn.