Nigeria: Ologun gba ‘Camp zero‘ lọwọ Boko Haram

Awọn ọmọ Nigeria n yayọ isẹgun nigbo Sambisa Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Awọn ọmọ ogun Naijiria ko sinmi lati fẹyin Boko Haram janlẹ.

Ileesẹ ologun Naijiria ni awọn ti tu ibuba awọn ikọ adukukulaja mọni nni Boko Haram ka, ninu igbo Sambisa.

Ibuba wọn naa, ti wọn pe ni ‘Camp Zero‘, lawọn ọmọogun Naijiria kọlu lasiko ti wọn sigun lọ ka Boko Haram mọle eyiti wọn pe ni operation DEEP PUNCH II.

Agbẹnusọ fun ileesẹ ologun orilẹ lorilẹede Naijiria, ọgagun Sani Usman lo kede eyi nilu Maiduguri.

Image copyright @HQNigerianArmy
Àkọlé àwòrán Awọn ologun Naijiria ko sinmi lati fẹyin Boko Haram janlẹ.

O ni, ikọ ọmọogun Naijiria ko ikogun to pọ nibuba Boko haram. Lara wọn ni awọn ọkọ ijagun oloro, oniruru ibọn, ọta ibọn, awọn iwe ẹsin lorisirisi, agolo, afẹfẹ idana gaasi pẹlu ajilẹ to ni wọn fi n se ado oloro alatọwọda, IEDs.

Alukoro fun ileesẹ ologun orilẹ lorilẹede Naijiria naa tun jẹ ko di mimọ pe awọn ọmọogun naa tun ba awọn ọkọ meje to jẹ ọkọ agbebọn, alupupu, aba ati awọn ọkọ miran jẹ nibẹ

Image copyright @HQNigerianArmy
Àkọlé àwòrán Ara ohun ti Boko Haram n polongo ni wipe awọn lodi si ẹkọ iwe

"Ni ọgbọnjọ osu kinni ọdun yi, awọn ọmọ ogun fi ija pẹẹta pẹlu awọn ọmọ ikọ Boko haram, ti wọn si gba ọkọ ijagun EMBT kan, ibọn AK-47, ibọn afẹfẹ tajutaju ati awọn iwe ẹsin lorisirisi pẹlu agolo afẹfẹ idana gaasi pẹlu ajilẹ."

Bakanaa ni wọn tun gba ọkọ ayọkẹlẹ Prado, Golf ati Mitsubishi pẹlu ọkọ meje to jẹ ọkọ agbebọn, alupupu."