Ọlọpa Spain mu eniyan mọkanla to nfi obinrin Naijiria sowo nabi

Aworan awọn obirin onisẹ nabi Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọpọ ọmọbinrin Naijiria ni wọn fi n sowo nabi ni Spain

Ọwọ awọn agbofinro lorilẹede Spain ti tẹ eniyan mokanla lori ẹsun pe wọn n ko awọn ọmọbinrin Naijiria wa silẹ sorilẹede naa lati fi se owo nabi

Wọ́n mu wọn nilu Zaragoza nibi ti awon ọlọpa ti doola ẹmi awọn obirin mẹrindinlogun lọwọ awọn to'n gbe won wa si ile okeere lati sowo nabi.

Wọn ni, iwadi fi han pe awọn onigbọwọ owo nabi yi maa fi oogun halẹ mọ awọn ọmọbinrin naa lọri ẹro ibanisọrọ ni lati se ifẹ ti wọn.

Bakanna ni awọn onigbọwọ owo nabi yi nfi ipa gba gbese tawọn ọmọbinrin naa ba jẹ wọn eyi to nii se pẹlu owo ti wọn fi gbe wọn lati Naijiria lọ silẹ okeere .

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aimọye ọmọ Naijiria ni wọn fi ẹtan mu lọsowo nabi nilẹ okeere.

Wọn nfi ẹtan gbe awọn obirin naa kuro nilu Benin wipẹ igbe aye to rọsọmu nduro de wọn nile Yuroopu.

Lẹyin igba ti wọn de Spain ni wọn sọ fun wọn pe, wọn yoo ma sisẹ nabi lati le da owo irinna wọn pada.

Awọn iya isalẹ wọnyi a si maa dun kukulaja mọ wọn lori foonu pe wọn ko gbọdọ mase sika adehun ti wọn sẹ.

Ẹgbẹ amunisin ọhun la gbọ wipe wọn pẹka de orilẹede Italy, Germany ati Denmark.