Ileejọ gbe asofin agba lẹyin lati tako iyansipo.

Ibrahim Magu, alaga EFCC Image copyright Efcc/Facebook
Àkọlé àwòrán Awọn asofin kọ lati yan Magu si ipo Alaga EFCC

Adajo ile ẹjo giga sọ pe ajọ to n gbogun tiwa ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria, EFCC kuna nigba lati ro pe ile asofin agba ko lẹtọ lati lodi si iyansipo alaga rẹ, Ibrahim Magu.

Ile ẹjo giga kan nilu Abuja ti gbe lẹyin ile asofin agba lori ipinnu rẹ lati lodi si iyansipo ọgbẹni Magu gẹgẹ bi alaga ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ (EFCC)

Ẹẹmeji ni Aarẹ Muhammadu Buhari ti fi orukọ Magu sọwọ si ile asofin agba ti wọn si ti daa pada pe ko yẹ fun ipo alaga ajọ naa.

Ninu idajo naa, adajo John Tsoho ni asise nla gbaa ni fun ajọ EFCC lati maa ro wi pẹ ile asofin agba ko lasẹ lati lodi si iyansipo alaga rẹ.

Ile ẹjọ giga ni ile asofin agba jare Magu

Nibayii, agbẹnusọ fun ile igbimọ asofin agba, Sẹnatọ Aliyu Sabi Abdullahi ni idajọ ile ẹjọ naa dun mọ awọn asofin ninu.

Nigba to'n ba awọn akọroyin sọrọ, o ni ''A fẹ fi asiko yi kan saara si ẹka idajọ ilẹ wa fun bi wọn ti se'n se daabo bo eto oselu tiwantiwa ati mimu agbega ba eto oselu ilẹ wa.''

Awọn asofin agba orilẹede yi ni wọn ti kọkọ lodi si iyansipo Magu nitori abọ iwadi awọn ọtẹlemuyẹ ilẹ wa lori rẹ.