Aisan jẹjẹrẹ asẹtọ ọkunrin paniyan ju jẹjẹrẹ ọyan lọ

Aworan apa isale Ọkunrin Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán aisan jẹjẹrẹ asẹtọ Ọkunrin n paniyan ju tatẹyin wa lọ nitori iye eniyan to n pe le si lagbaye

Fun igba akọkọ nile Gẹẹsi, iyẹ awọn Ọkunrin to ku nipa aisan jẹjẹrẹ asẹtọ ọkunrin ti bori iyẹ awọn ọbinrin to n ku nipasẹ aisan jẹjẹrẹ ọyan, atọka ti fihan bẹẹ.

Eyi ti fihan wipe bi awọn agbalagba se n pọ si lawujọ ni ọpọlọpọ ọkunrin n ku nitori aisan jẹjẹrẹ asẹtọ.

Ajọ to n gbogun ti aisan jẹjẹrẹ nile Geesi (Prostate Cancer UK), ti ni igbega to n ba iwadi ati iwosan arun jẹjẹrẹ oyan ti n so eso rere, eyi to mu ki alekun ba owo ti wọn n na, to si le se anfani fun awọn to ni aisan jẹjẹrẹ asẹtọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aisan jẹjẹrẹ asẹtọ Ọkunrin lo wọpọ julọ ni ilẹ Geesi

Lorilẹede Gẹẹsi, aisan jẹjẹrẹ to paniyan ju ni ti ọna ọfun ati ti isale ikun, ti aisan jẹjẹrẹ asẹtọ Ọkunrin si jẹ ikẹta ninu awọn aisan to paniju lọ ni ilẹ Geesi.

Adari iroyin fun ile-ise to n risi aisan jẹjẹrẹ nile Geesi , Micheal Chapman sọ wipe idi ti aisan jẹjẹrẹ fi n paniyan ju tatẹyinwa lọ niwipe ojojumọ ni iye awọn eniyan n pọsi lagbaye ati wipe awọn Ọkunrin n pe laye ju ti tẹlẹ lọ.

Amin Aisan jẹjẹrẹ asẹtọ Ọkunrin

  • Ki itọ o ma joni nidi ti Ọ̀mọkunrin ba fe tọ
  • Isoro lati le tọ tabi lati da itọ duro nigba ti Ọ̀mọkunrin ba nsẹyọ
  • Ki Ọ̀mọkunrin ma tọ nigbakugba loru
  • Ailemu itọ duro
  • Ki itọ o se tabi ki o ma jade daradara
  • Ki Ọ̀mọkunrin o ma tọ itọ ẹjẹ
  • Ki ẹsẹ ati ibi Ọ̀mọkunrin o ma wu
  • Irọra ni ibadi, ẹsẹ ati ika ẹsẹ
  • Irọra ninu egungun to le jasi ki eegun o run