Ọbasanjọ:Lẹta mi si Buhari ko wa fun ẹtanu

Oloye Olusẹgun Ọbasanjọ
Àkọlé àwòrán Ọbasanjọ ni ojuse gbogbo ọmọ Naijiria ni lati ri si idagbasoke ilẹ baba wa

Aarẹ tẹlẹ lorilẹede yi, Oloye Olusẹgun Ọbasanjọ ti yọ suti ete sile asofin apapọ ilẹ wa ati ajọ to wa fun igbesẹ buure, laa re taa mọ si federal character commission.

O ni ẹka mejeeji yi ni ko maa ge iyẹ aarẹ Muhammadu Buhari lori iwa aise deede to n hu nidi pinpin ipo agbara lorilẹede yi.

Bakanaa ni Oloye Ọbasanjọ ni iwe toun kọ laipẹ yi si aarẹ Buhari kii se ti ẹtanu rara tabi ti ija amọ o da lori bi ọrọ orilẹede yi se jẹ oun logun si ni.

Ibudo awọn akọroyin nilu Abẹokuta ni Oloye Ọbasanjọ ti sisọ loju ọrọ yi ni kete to sefilọlẹ ẹgbẹ alajumọse, ẹka tipinlẹ ogun tan.

Ojuse ile asofin apapọ ni lati maa tọ ẹka alasẹ sọna lori iyansipo nlanla

Oloye Ọbasanjọ ni o dabi ẹnipe gbogbo wa ti n fi ọwọ yẹpẹrẹ mu idagbasoke orilẹede wa, oorekoore si lo yẹ ki onikaluku wa maa kọbi ara si eto ilọsiwaju ilẹ baba wa, latipasẹ awọn eto onidagbasoke loniranran.

"Ojuse ajọ buure,laare, ikan ko gbọdọ ju ọkan lọ ni lati ri daju pe o n se atọna fun ẹka alasẹ orilẹede yi, ki wọn lee sawari awọn eeyan to dantọsawọn ipo kanrin-kanrin yika orilẹede yi, ki awọn ipo yi ma si wa lọwọ ẹya kansoso tabi agbegbe kan gẹgẹ bo se n waye bayi."

Taa ba si fẹ kiru isẹlẹ bayi maa waye, ojuse ile asofin apapọ ati ti ajs buure, laare ni latitete maa ke gbajare sita tabi tako awọn iyansipo naaeyi tawọn ẹka alasẹ ba se, to si tako ilana ofin orilẹede yi.