ÀJọ UN bu ẹnu àtẹ́ lu bí Nigeria se kó àwọn ọmọ Cameroon pada silu wọn

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán ÀJọ UN bu ẹnu àtẹ́ lu bí Nigeria se kó àwọn ọmọ Cameroon pada silu wọn

Ajọ isọkan agbaye, United Nations sọ wipe tipa tipa ni orilẹede Naijiria fi ko ẹgbẹ awọn ọmọ orilẹede Cameroon kan to ngbe lorilẹede Naijiria pada si ilu wọn. Ajọ UN sọ pe Orilẹede Naijiria ru ofin ojuse wọn ninu awọn orilẹede agbaye lati da abo bo awọn atipo.

Ẹgbẹ ẹlẹni mẹtadinlaadọta to nsọ ede Gẹẹsi ni orilẹede Cameroon to ya kuro lati orilẹede wọn lati wa gbe ni Naijiria pẹlu adari wọn, Julius Sisiku Ayuk Tabe ni wọn ko kuro ni orilẹede Naijiria lọ si orilẹede Cameroon lẹyin ti wọn ko wọn ni ilu Abuja ni ibẹrẹ osu kini ọdun yii.

Fifi ipa da wọn pada ni wọn sọ pe o lodi si ofin to de orilẹede kan lati da abo bo awọn to ba wa se tabi bẹbẹ lati se atipo ni orilẹede naa lati orilẹede mii.

Ile isẹ ajọ UN to nrisi ọrọ awọn atipo, UNHCR ran orilẹede Naijiria leti ojuse rẹ labẹ ofin agbaye ati ofin ilẹ Naijiria. UNHCR wa rọ ijọba orilẹede Naijiria lati siwọ ninu fifi ipa da awọn atipo ọmọ Cameroon pada si orilẹede kowa wọn.

Wọn da fifi panpẹ ọba mu Ayuk Tabe lori ẹsun pe o nkopa ninu awọn ipade abẹlẹ kọọkan lodi si orilẹede Cameroon.

Ohun to mu awọn atipo Cameroon yii wa si Naijiria

  • O le lọdun ti igbesẹ awọn afẹhonu han ni orilẹede Cameroon ti fa ọpọlọpọ wahala
  • Awọn apa ibi ti wọn ti nsọ ede Gẹẹsi nsọ wipe ijọba atawọn elede Faranse ti fọwọ rọ awọn sẹgbẹ kan fun ọdun gbọọrọ
  • Awọn afẹhonu han yii npe fun ki wọn da ijọba alapapọ pada tabi didaduro awọn ara ilẹ Cameroon
  • Ni idakeji, awọn to nsọ ede Gẹẹsi maa nsọ wipe wọn yọ nyọ wọn kuro lara awọn lọgalọga osisẹ ijọba ti wọn si nlo awọn elede Faranse
  • Bi o tilẹ jẹ wipe ofin fun ede mejeeji ni ipo kan naa.