Wọ́n pín rọ́ba ìdáàbòbò Condom fún àwọn eléré orí pápá

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Wọn pin ẹgbẹrun lọna aadọfa rọba idaabobo nibi idije Olympic

Ni ọjọ kini, osu keji ọdun yii, ibugbe ti wọn kọ fun awọn elere idije Olympic to wa ni Pyeongchang ki nkan ti o fẹrẹẹ to ẹgbẹrun mẹta elere ori papa lati igbimọ orilẹede aadọrun to nkopa ninu idije Olympic.

Lakoko awọn ere idaraya ori papa naa to bọ si akoko otutu, awọn to se agbekalẹ eto naa yoo pin ẹgbẹrun lọna aadọfa rọba idaabobo condom fun awọn elere ori papa.

Idije oniruuru ere ori papa naa yoo bẹrẹ ni ọsẹ to mbọ bẹẹ si ni awọn alakoso eto nreti idije Olympic to bọ si akoko otutu to pọju ninu itan.

Ẹwẹ, lai fẹ ki awọn to ti gbalejo idije alakoko otutu yii tẹlẹ gba ipo mọ wọn lọwọ, awọn to nse akoso ti tọtẹ yii ni orilẹede South Korea ti pin rọba idaabobo ẹgbẹrun lọna aadọfa fun awọn akopa. Eyi fi ẹgbẹrun mẹwa ju iye ti wọn pin sita lakoko idije Olympics to kọja ni Sochi orilẹede Russia

Awọn kan sọ pe o jẹ afihan jijẹ ẹni daradara si awọn akopa

Ko ma baa ya yin lẹnu, ẹ ka nipa itan rọba idaabobo ni Olympic

  • Ni idije Olympics ti ọdun 1988 to jẹ akoko oru, wọn pin rọba idaabobo fun 'gba akọkọ ni gbangba ni South Korea lati din aranka arun HIV ku
  • Ọdun 1944 to jẹ idije Olympics ni akoko otutu, awọn alakoso idije pin rọba idaabobo lọfẹ fun awọn akopa, oniroyin atawọn eekan gẹgẹ bi ipolongo ni ilu Norway
  • Ni ọdun 2000 to jẹ idije Olympics lakoko oru, awọn alakoso pin ẹgbẹrun lọna aadọrun rọba idaabobo fun awn elere ori papa ni Sidney, olilẹede Australia
  • Ọdun 2010 lakoko otutu, ibudo ilẹ Britain fun idojukọ aisan pin nkan bii ẹgbẹrun lọna ọgọrun rọba idaabobo fun awọn elere ori papa atawọn osisẹ ni awọn ibudo ti idije ti waye ni Vancouver
  • Ni ọdun 2016 to jẹ idije eyi to sunmọ ju to si jẹ akoko oru, awọn alakoso se agbekalẹ irinwo le laadọta rọba idaabobo lati pin fun awọn elere ori papa ni Rio de Janeiro. Eyi ja si rọba idaabobo mejilelogoji fun eniyan kan.